Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 3:8-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. O si nfò soke, o duro, o si bẹrẹ si rin, o si ba wọn wọ̀ inu tẹmpili lọ, o nrìn, o si nfò, o si nyìn Ọlọrun.

9. Gbogbo enia si ri i, o nrìn, o si nyìn Ọlọrun:

10. Nwọn si mọ̀ pe on li o ti joko nṣagbe li ẹnu-ọ̀nà Daradara ti tẹmpili: hà si ṣe wọn, ẹnu si yà wọn gidigidi si ohun ti o ṣe lara rẹ̀.

11. Bi arọ ti a mu larada si ti di Peteru on Johanu mu, gbogbo enia jumọ sure jọ tọ̀ wọn lọ ni iloro ti a npè ni ti Solomoni, ẹnu yà wọn gidigidi.

12. Nigbati Peteru si ri i, o dahùn wi fun awọn enia pe, Ẹnyin enia Israeli, ẽṣe ti ha fi nṣe nyin si eyi? tabi ẽṣe ti ẹnyin fi tẹjumọ́ wa, bi ẹnipe agbara tabi iwa-mimọ́ wa li awa fi ṣe ti ọkunrin yi fi nrin?

13. Ọlọrun Abrahamu, ati ti Isaaki, ati ti Jakọbu, Ọlọrun awọn baba wa, on li o ti yìn Jesu Ọmọ rẹ̀ logo; ẹniti ẹnyin ti fi le wọn lọwọ, ti ẹnyin si sẹ́ niwaju Pilatu, nigbati o ti pinnu rẹ̀ lati da a silẹ.

14. Ṣugbọn ẹnyin sẹ́ Ẹni-Mimọ́ ati Olõtọ nì, ẹnyin si bere ki a fi apania fun nyin;

15. Ẹnyin si pa Olupilẹṣẹ ìye, ẹniti Ọlọrun si ti ji dide kuro ninu okú; ẹlẹri eyiti awa nṣe.

16. Ati orukọ rẹ̀, nipa igbagbọ́ ninu orukọ rẹ̀, on li o mu ọkunrin yi lara le, ẹniti ẹnyin ri ti ẹ si mọ̀: ati igbagbọ́ nipa rẹ̀ li o fun u ni dida ara ṣáṣa yi li oju gbogbo nyin.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 3