Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 3:13-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ọlọrun Abrahamu, ati ti Isaaki, ati ti Jakọbu, Ọlọrun awọn baba wa, on li o ti yìn Jesu Ọmọ rẹ̀ logo; ẹniti ẹnyin ti fi le wọn lọwọ, ti ẹnyin si sẹ́ niwaju Pilatu, nigbati o ti pinnu rẹ̀ lati da a silẹ.

14. Ṣugbọn ẹnyin sẹ́ Ẹni-Mimọ́ ati Olõtọ nì, ẹnyin si bere ki a fi apania fun nyin;

15. Ẹnyin si pa Olupilẹṣẹ ìye, ẹniti Ọlọrun si ti ji dide kuro ninu okú; ẹlẹri eyiti awa nṣe.

16. Ati orukọ rẹ̀, nipa igbagbọ́ ninu orukọ rẹ̀, on li o mu ọkunrin yi lara le, ẹniti ẹnyin ri ti ẹ si mọ̀: ati igbagbọ́ nipa rẹ̀ li o fun u ni dida ara ṣáṣa yi li oju gbogbo nyin.

17. Njẹ nisisiyi, ará, mo mọ̀ pe, nipa aimọ̀ li ẹnyin fi ṣe e, gẹgẹ bi awọn olori nyin pẹlu ti ṣe.

18. Ṣugbọn ohun ti Ọlọrun ti sọ tẹlẹ lati ẹnu gbogbo awọn woli wá pe, Kristi rẹ̀ yio jìya, on li o muṣẹ bẹ̃.

19. Nitorina ẹ ronupiwada, ki ẹ si tun yipada, ki a le pa ẹ̀ṣẹ nyin rẹ́, ki akoko itura ba le ti iwaju Oluwa wá,

20. Ati ki o ba le rán Kristi, ti a ti yàn fun nyin, aní Jesu;

21. Ẹniti ọrun kò le ṣaima gbà titi di igba imupadà ohun gbogbo, ti Ọlọrun ti sọ lati ẹnu awọn woli rẹ̀ mimọ́ ti nwọn ti mbẹ nigbati aiye ti ṣẹ̀.

22. Mose sa wipe, Oluwa Ọlọrun nyin yio gbé woli kan dide fun nyin ninu awọn arakunrin nyin, bi emi; on ni ẹnyin o ma gbọ́ tirẹ̀ li ohun gbogbo ti yio ma sọ fun nyin.

23. Yio si ṣe, olukuluku ọkàn ti kò ba gbọ ti woli na, on li a o parun patapata kuro ninu awọn enia.

24. Ani gbogbo awọn woli lati Samueli wá, ati awọn ti o tẹle e, iye awọn ti o ti sọrọ, nwọn sọ ti ọjọ wọnyi pẹlu.

25. Ẹnyin li ọmọ awọn woli, ati ti majẹmu tí Ọlọrun ti ba awọn baba nyin dá nigbati o wi fun Abrahamu pe, Ati ninu irú-ọmọ rẹ li a ti fi ibukun fun gbogbo idile aiye.

26. Nigbati Ọlọrun jí Jesu Ọmọ rẹ̀ dide, o kọ́ rán a si nyin lati busi i fun nyin, nipa yiyi olukuluku nyin pada kuro ninu iwa buburu rẹ̀.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 3