Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 27:8-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Nigbati a si fi agbara kaka kọja rẹ̀, awa de ibi ti a npè ni Ebute Yiyanjú, ti o sunmọ ibiti ilu Lasea ti wà ri.

9. Nigbati a si ti sọ ọjọ pipọ nù, ti a-ti ta igbokun wa idi ewu tan, nitori Awẹ ti kọja tan, Paulu da imọran,

10. O si wi fun wọn pe, Alàgba, mo woye pe iṣikọ̀ yi yio li ewu ati òfo pipọ, kì iṣe kìki ti ẹrù ati ti ọkọ̀, ṣugbọn ti ẹmí wa pẹlu.

11. Ṣugbọn balogun ọrún gbà ti olori ọkọ̀ ati ti ọlọkọ̀ gbọ́, jù ohun wọnni ti Paulu wi lọ.

12. Ati nitori ebute na kò rọrùn lati lo akoko otutu nibẹ̀, awọn pipọ si damọran pe, ki a lọ kuro nibẹ̀, bi nwọn ó le làkàka de Fenike lati lo akoko otutu, ti iṣe ebute Krete ti o kọju si òsi ìwọ õrùn, ati ọtún ìwọ õrùn.

13. Nigbati afẹfẹ gusù si nfẹ jẹ́jẹ, ti nwọn ṣebi ọwọ awọn tẹ̀ ohun ti nwọn nwá, nwọn ṣikọ̀, nwọn npá ẹba Krete lọ.

14. Kò si pẹ lẹhin na ni ìji ti a npè ni Eurakuilo fẹ lù u.

15. Nigbati o si ti gbé ọkọ̀, ti kò si le dojukọ ìji na, awa jọwọ rẹ̀, o ngbá a lọ.

16. Nigbati o si gbá a lọ labẹ erekuṣu kan ti a npè ni Klauda, o di iṣẹ pipọ ki awa ki o to le sunmọ igbaja.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 27