Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 27:12-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ati nitori ebute na kò rọrùn lati lo akoko otutu nibẹ̀, awọn pipọ si damọran pe, ki a lọ kuro nibẹ̀, bi nwọn ó le làkàka de Fenike lati lo akoko otutu, ti iṣe ebute Krete ti o kọju si òsi ìwọ õrùn, ati ọtún ìwọ õrùn.

13. Nigbati afẹfẹ gusù si nfẹ jẹ́jẹ, ti nwọn ṣebi ọwọ awọn tẹ̀ ohun ti nwọn nwá, nwọn ṣikọ̀, nwọn npá ẹba Krete lọ.

14. Kò si pẹ lẹhin na ni ìji ti a npè ni Eurakuilo fẹ lù u.

15. Nigbati o si ti gbé ọkọ̀, ti kò si le dojukọ ìji na, awa jọwọ rẹ̀, o ngbá a lọ.

16. Nigbati o si gbá a lọ labẹ erekuṣu kan ti a npè ni Klauda, o di iṣẹ pipọ ki awa ki o to le sunmọ igbaja.

17. Nigbati nwọn si gbé e soke, nwọn nṣe iranlọwọ, nwọn ndì ọkọ ni isalẹ; nigbati nwọn si bẹ̀ru ki a ma ba gbá wọn sori iyanrìn diẹ̀, nwọn tagbokun, nwọn si ngbá kiri.

18. Bi awa si ti nṣe lãlã gidigidi ninu ìji na, ni ijọ keji nwọn kó nkan dà si omi lati mu ọkọ̀ fẹrẹ;

19. Ati ni ijọ kẹta, a fi ọwọ́ ara wa kó ohun èlo ọkọ̀ danu.

20. Nigbati õrùn ati irawọ kò si hàn li ọjọ pipọ, ti ìji na kò si mọ̀ niwọn fun wa, abá a-ti-là kò si fun wa mọ́.

21. Nigbati nwọn wà ni aijẹun li ọjọ pipọ, nigbana Paulu dide larin wọn, o ni, Alàgba, ẹnyin iba ti gbọ́ ti emi, ki a máṣe ṣikọ̀ kuro ni Krete, ewu ati òfo yi kì ba ti ba wa.

22. Njẹ nisisiyi mo gbà nyin niyanju, ki ẹ tújuka: nitori kì yio si òfo ẹmí ninu nyin, bikoṣe ti ọkọ̀.

23. Nitori angẹli Ọlọrun, ti ẹniti emi iṣe, ati ẹniti emi nsìn, o duro tì mi li oru aná,

24. O wipe, Má bẹ̀ru, Paulu; iwọ kò le ṣaima duro niwaju Kesari: si wo o, Ọlọrun ti fi gbogbo awọn ti o ba ọ wọkọ̀ pọ̀ fun ọ.

25. Njẹ nitorina, alàgba, ẹ daraya: nitori mo gbà Ọlọrun gbọ́ pe, yio ri bẹ̃ gẹgẹ bi a ti sọ fun mi.

26. Ṣugbọn a ó gbá wa jù si erekuṣu kan.

27. Ṣugbọn nigbati o di oru ijọ kẹrinla, ti awa ngbá sihin sọhún ni Adria, larin ọganjọ awọn atukọ̀ tànmã pe, awọn sunmọ eti ilẹ kan;

28. Nigbati nwọn si wọ̀n okun, nwọn ri i o jìn li ogún àgbaká: nigbati nwọn si sún siwaju diẹ, nwọn si tún wọ̀n okun, nwọn ri i o jìn ni àgbaká mẹ̃dogun.

29. Nigbati nwọn bẹ̀ru ki nwọn ki o máṣe gbá lù ibi okuta, nwọn sọ idakọró mẹrin silẹ ni idi ọkọ̀, nwọn nreti ojumọ́.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 27