Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 27:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Bi a si ti pinnu rẹ̀ pe ki a wọ̀ ọkọ lọ si Itali, nwọn fi Paulu, ati awọn ondè miran kan pẹlu, le balogun ọrún kan lọwọ, ti a npè ni Juliu, ti ẹgbẹ ọmọ-ogun Augustu.

2. Nigbati a si wọ̀ ọkọ̀ Adramittiu kan, ti nfẹ lọ si awọn ilu ti o wà leti okun Asia, awa ṣikọ̀: Aristarku, ara Makedonia ti Tessalonika, wà pẹlu wa.

3. Ni ijọ keji awa de Sidoni. Juliu si ṣe inu rere si Paulu, o si bùn u láye ki o mã tọ̀ awọn ọrẹ́ rẹ̀ lọ lati ri itọju.

4. Nigbati awa si ṣikọ̀ nibẹ̀, awa lọ lẹba Kipru, nitoriti afẹfẹ ṣọwọ òdi.

5. Nigbati awa ré okun Kilikia on Pamfilia kọja, awa de Mira Likia.

6. Nibẹ̀ ni balogun ọrún si ri ọkọ̀ Aleksandria kan, ti nlọ si Itali; o si fi wa sinu rẹ̀.

7. Nigbati awa nlọ jẹ́jẹ li ọjọ pipọ, ti awa fi agbara kaka de ọkankan Knidu, ti afẹfẹ kò bùn wa làye, awa lọ lẹba Krete, li ọkankan Salmone;

8. Nigbati a si fi agbara kaka kọja rẹ̀, awa de ibi ti a npè ni Ebute Yiyanjú, ti o sunmọ ibiti ilu Lasea ti wà ri.

9. Nigbati a si ti sọ ọjọ pipọ nù, ti a-ti ta igbokun wa idi ewu tan, nitori Awẹ ti kọja tan, Paulu da imọran,

Ka pipe ipin Iṣe Apo 27