Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 26:18-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Lati là wọn li oju, ki nwọn ki o le yipada kuro ninu òkunkun si imọlẹ, ati kuro lọwọ agbara Satani si Ọlọrun, ki nwọn ki o le gbà idariji ẹ̀ṣẹ, ati ogún pẹlu awọn ti a sọ di mimọ́ nipa igbagbọ ninu mi.

19. Nitorina, Agrippa ọba, emi kò ṣe aigbọran si iran ọ̀run na.

20. Ṣugbọn mo kọ́ sọ fun awọn ti o wà ni Damasku, ati ni Jerusalemu, ati já gbogbo ilẹ Judea, ati fun awọn Keferi, ki nwọn ki o ronupiwada, ki nwọn si yipada si Ọlọrun, ki nwọn mã ṣe iṣẹ ti o yẹ si ironupiwada.

21. Nitori nkan wọnyi li awọn Ju ṣe mu mi ni tẹmpili, ti nwọn si fẹ pa mi.

22. Ṣugbọn bi mo si ti ri iranlọwọ gbà lọdọ Ọlọrun, mo duro titi o fi di oni, mo njẹri fun ati ewe ati àgba, emi kò sọ ohun miran bikoṣe ohun ti awọn woli ati Mose ti wipe yio ṣẹ:

23. Pe, Kristi yio jìya, ati pe nipa ajinde rẹ̀ kuro ninu oku, on ni yio kọ́ kede imọlẹ fun awọn enia ati fun awọn Keferi.

24. Bi o si ti nsọ t'ẹnu rẹ̀, Festu wi li ohùn rara pe, Paulu, ori rẹ bajẹ; ẹkọ́ akọjù ba ọ li ori jẹ.

25. Ṣugbọn Paulu wipe, Ori mi kò bajẹ, Festu ọlọlá julọ; ṣugbọn ọ̀rọ otitọ ati ti ìwa airekọja li emi nsọ jade.

26. Nitori ọba mọ̀ nkan gbogbo wọnyi, niwaju ẹniti emi nsọ̀rọ li aibẹ̀ru: nitori mo gbagbọ pe ọkan ninu nkan wọnyi kò pamọ fun u, nitoriti a kò ṣe nkan yi ni ìkọkọ.

27. Agrippa ọba, iwọ gbà awọn woli gbọ́? Emi mọ̀ pe, iwọ gbagbọ́.

28. Agrippa si wi fun Paulu pe, Pẹlu ọrọ iyanju diẹ si i, iwọ iba sọ mi di Kristiani.

29. Paulu si wipe, Iba wu Ọlọrun, yala pẹlu ãpọn diẹ tabi pipọ pe, ki o maṣe iwọ nikan, ṣugbọn ki gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ mi loni pẹlu le di iru enia ti emi jẹ laisi ẹwọn wọnyi.

30. Nigbati o si sọ nkan wọnyi tan, ọba dide, ati bãlẹ, ati Bernike, ati awọn ti o ba wọn joko:

Ka pipe ipin Iṣe Apo 26