Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 23:3-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Nigbana ni Paulu wi fun u pe, Ọlọrun yio lù ọ, iwọ ogiri ti a kùn li ẹfun: iwọ joko lati dajọ mi ni gẹgẹ bi ofin, iwọ si pè ki a lù mi li òdi si ofin?

4. Awọn ti o duro tì i si wipe, Olori alufa Ọlọrun ni iwọ ngàn?

5. Paulu si wipe, Ará, emi kò mọ̀ pe olori alufa ni: nitori a ti kọ ọ pe, Iwọ kò gbọdọ sọ̀rọ olori awọn enia rẹ ni buburu.

6. Ṣugbọn nigbati Paulu ṣakiyesi pe, apakan wọn jẹ Sadusi, apakan si jẹ Farisi, o kigbe ni igbimọ pe, Ará, Farisi li emi, ọmọ Farisi: nitori ireti ati ajinde okú li a ṣe ba mi wijọ.

7. Nigbati o si ti wi eyi, iyapa de lãrin awọn Farisi ati awọn Sadusi: ajọ si pin meji.

8. Nitoriti awọn Sadusi wipe, kò si ajinde, tabi angẹli, tabi ẹmí: ṣugbọn awọn Farisi jẹwọ mejeji.

9. O si di ariwo nla: ninu awọn akọwe ti o wà li apa ti awọn Farisi dide, nwọn njà, wipe, Awa kò ri ohun buburu kan lara ọkunrin yi: ki si ni bi ẹmi kan tabi angẹli kan li o ba a sọ̀rọ?

10. Nigbati iyapa si di nla, ti olori ogun bẹ̀ru ki Paulu ki o má bà di fifaya lọwọ wọn, o paṣẹ pe ki awọn ọmọ-ogun sọkalẹ lọ lati fi ipá mu u kuro lãrin wọn, ki nwọn si mu u wá sinu ile-olodi.

11. Li oru ijọ na Oluwa duro tì i, o si wipe, Tujuka: nitori bi iwọ ti jẹri fun mi ni Jerusalemu, bẹ̃ni iwọ kò le ṣaijẹrí ni Romu pẹlu.

12. Nigbati ilẹ mọ́, awọn Ju kan dimọlu, nwọn fi ara wọn bu pe, awọn kì yio jẹ bẹ̃li awọn kì yio mu, titi awọn ó fi pa Paulu.

13. Awọn ti o ditẹ yi si jù ogoji enia lọ.

14. Nwọn si tọ̀ olori awọn alufa ati awọn àgbagba lọ, nwọn si wipe, Awa ti fi èpe nla bu ara wa pe, a kì yio tọ́ ohun nkan wò titi awa ó fi pa Paulu.

15. Njẹ nisisiyi ki ẹnyin pẹlu ajọ igbimọ wi fun olori-ogun, ki o mu u sọkalẹ tọ̀ nyin wá, bi ẹnipe ẹnyin nfẹ wadi ọ̀ran rẹ̀ dajudaju: ki o to sunmọ itosi, awa ó si ti mura lati pa a.

16. Nigbati ọmọ arabinrin Paulu si gburó idena wọn, o lọ, o si wọ̀ inu ile-olodi lọ, o si sọ fun Paulu.

17. Paulu si pè ọkan ninu awọn balogun ọrún sọdọ rẹ̀, o ni, Mu ọmọkunrin yi tọ̀ olori-ogun lọ: nitori o ni nkan lati sọ fun u.

18. O mu u, o si sìn i lọ sọdọ olori-ogun, o si wipe, Paulu ondè pè mi sọdọ rẹ̀, o si bẹ̀ mi pe ki emi mu ọmọkunrin yi tọ̀ ọ wá, ẹniti o ni nkan lati sọ fun ọ.

19. Olori-ogun fà a lọwọ, o si lọ si apakan, o si bi i lere nikọkọ pe, Kili ohun ti iwọ ni isọ fun mi?

20. O si wipe, Awọn Ju fi ìmọ ṣọkan lati wá ibẹ̀ ọ ki o mu Paulu sọkalẹ wá si ajọ igbimọ li ọla, bi ẹnipe iwọ nfẹ bère nkan dajudaju nipa rẹ̀.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 23