Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 22:10-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Mo si wipe, Kini ki emi ki o ṣe, Oluwa? Oluwa si wi fun mi pe, Dide, ki o si lọ si Damasku; nibẹ̀ li a o si sọ ohun gbogbo fun ọ ti a yàn fun ọ lati ṣe.

11. Bi emi kò si ti le riran nitori itànṣan imọlẹ na, a ti ọwọ́ awọn ti o wà lọdọ mi fà mi, mo si de Damasku.

12. Ẹnikan si tọ̀ mi wá, Anania, ọkunrin olufọkansìn gẹgẹ bi ofin, ti o li orukọ rere lọdọ gbogbo awọn Ju ti o ngbe ibẹ̀.

13. O si duro tì mi, o si wi fun mi pe, Saulu arakunrin, riran. Ni wakati kanna mo si ṣiju soke wò o.

14. O si wipe, Ọlọrun awọn baba wa yàn ọ, lati mọ̀ ifẹ rẹ̀, ati lati ri Olõtọ nì, ati lati gbọ́ ohùn li ẹnu rẹ̀,

15. Ki iwọ ki o le ṣe ẹlẹri rẹ̀ fun gbogbo enia, li ohun ti iwọ ti ri ti iwọ si ti gbọ́.

16. Njẹ nisisiyi kini iwọ nduro de? Dide, ki a si baptisi rẹ, ki o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ nù, ki o si mã pè orukọ Oluwa.

17. O si ṣe pe, nigbati mo pada wá si Jerusalemu, ti mo ngbadura ni tẹmpili mo bọ si ojuran;

18. Mo si ri i, o wi fun mi pe, Yara, ki o si jade kuro ni Jerusalemu kánkán: nitori nwọn kì yio gbà ẹrí rẹ nipa mi.

19. Emi si wipe, Oluwa, awọn pãpã mọ̀ pe, emi a ti mã sọ awọn ti o gbà ọ gbọ sinu tubu, emi a si mã lù wọn ninu sinagogu gbogbo:

20. Nigbati a si ta ẹ̀jẹ Stefanu ẹlẹri rẹ silẹ, emi na pẹlu duro nibẹ̀, mo si li ohùn si ikú rẹ̀, mo si nṣe itọju aṣọ awọn ẹniti o pa a.

21. O si wi fun mi pe, Mã lọ: nitori emi ó rán ọ si awọn Keferi lokere réré.

22. Nwọn si fi etí si i titi de ọ̀rọ yi, nwọn si gbé ohùn wọn soke wipe, Ẹ mu irú eyiyi kuro li aiye: nitori kò yẹ ki o wà lãye.

23. Bi nwọn si ti nkigbe, ti nwọn si wọ́n aṣọ wọn silẹ, ti nwọn nku ekuru si oju ọrun,

24. Olori ogun paṣẹ pe ki a mu u wá sinu ile-olodi, o ni ki a fi ẹgba bi i lẽre; ki on ki o le mọ̀ itori ohun ti nwọn ṣe nkigbe le e bẹ̃.

25. Bi nwọn si ti fi ọsán dè e, Paulu bi balogun ọrún ti o duro tì i pe, O ha tọ́ fun nyin lati nà ẹniti iṣe ará Romu li aijẹbi?

26. Nigbati balogun ọrún si gbọ́, o lọ, o wi fun olori-ogun pe, Kili o fẹ ṣe yi: nitori ọkunrin yi ara Romu ni iṣe.

27. Olori-ogun si de, o si bi i pe, Sọ fun mi, ara Romu ni iwọ iṣe? O si wipe, Bẹ̃ni.

28. Olori-ogun si dahùn wipe, Owo pupọ ni mo fi rà ọlá ibilẹ yi. Paulu si wipe, Ṣugbọn a bí emi bẹ̃ ni.

29. Nitorina awọn ti o mura lati bi i lẽre kuro lọdọ rẹ̀: lojukanna olori-ogun pẹlu si bẹ̀ru, nigbati o mọ̀ pe ara Romu ni iṣe, ati nitori o ti dè e.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 22