Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 21:4-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nigbati a si ri awọn ọmọ-ẹhin, awa duro nibẹ̀ ni ijọ meje: awọn ẹniti o tipa Ẹmí wi fun Paulu pe, ki o máṣe lọ si Jerusalemu.

5. Nigbati a si ti lò ọjọ wọnni tan, awa jade, a si mu ọ̀na wa pọ̀n; gbogbo nwọn si sìn wa, pẹlu awọn obinrin ati awọn ọmọde titi awa fi jade si ẹhin ilu: nigbati awa si gunlẹ li ebute, awa si gbadura.

6. Nigbati a si ti dágbere fun ara wa, awa bọ́ si ọkọ̀; ṣugbọn awọn si pada lọ si ile wọn.

7. Nigbati a si ti pari àjo wa lati Tire, awa de Ptolemai; nigbati a si kí awọn ará, awa si ba wọn gbé ni ijọ kan.

8. Ni ijọ keji awa lọ kuro, a si wá si Kesarea: nigbati awa si wọ̀ ile Filippi Efangelisti, ọkan ninu awọn meje nì; awa si wọ̀ sọdọ rẹ̀.

9. Ọkunrin yi si li ọmọbinrin mẹrin, wundia, ti ima sọtẹlẹ.

10. Bi a si ti wà nibẹ̀ li ọjọ pipọ, woli kan ti Judea sọkalẹ wá, ti a npè ni Agabu.

11. Nigbati o si de ọdọ wa, o mu amure Paulu, o si de ara rẹ̀ li ọwọ́ on ẹsẹ, o si wipe, Bayi li Ẹmí Mimọ́ wi, Bayi li awọn Ju ti o wà ni Jerusalemu yio de ọkunrin ti o ni amure yi, nwọn o si fi i le awọn Keferi lọwọ.

12. Nigbati a si ti gbọ́ nkan wọnyi, ati awa, ati awọn ará ibẹ̀ na bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe gòke lọ si Jerusalemu.

13. Nigbana ni Paulu dahùn wipe, Ewo li ẹnyin nṣe yi, ti ẹnyin nsọkun, ti ẹ si nmu ãrẹ̀ ba ọkàn mi; nitori emi mura tan, kì iṣe fun didè nikan, ṣugbọn lati kú pẹlu ni Jerusalemu, nitori orukọ Jesu Oluwa.

14. Nigbati a kò le pa a li ọkàn dà, awa dakẹ, wipe, Ifẹ ti Oluwa ni ki a ṣe.

15. Lẹhin ijọ wọnni, awa palẹmọ, a si gòke lọ si Jerusalemu.

16. Ninu awọn ọmọ-ẹhin lati Kesarea ba wa lọ, nwọn si mu Mnasoni ọmọ-ẹhin lailai kan pẹlu wọn, ará Kipru, lọdọ ẹniti awa ó gbé wọ̀.

17. Nigbati awa si de Jerusalemu, awọn arakunrin si fi ayọ̀ gbà wa.

18. Ni ijọ keji awa ba Paulu lọ sọdọ Jakọbu; gbogbo awọn alàgba si wà nibẹ̀.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 21