Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 2:10-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Frigia, ati Pamfilia, Egipti, ati ẹkùn Libia niha Kirene, ati awọn atipo Romu, awọn Ju ati awọn alawọṣe Ju,

11. Awọn ara Krete ati Arabia, awa gbọ́ nwọn nsọ̀rọ iṣẹ iyanu nla Ọlọrun li ède wa.

12. Hà si ṣe gbogbo wọn, o si rú wọn lojú, nwọn wi fun ara wọn pe, Kili a le mọ̀ eyi si?

13. Ṣugbọn awọn ẹlomiran nṣẹ̀fẹ nwọn si wipe, Awọn ọkunrin wọnyi kún fun waini titun.

14. Ṣugbọn Peteru dide duro pẹlu awọn mọkanla iyokù, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o si wi fun wọn gbangba pe, Ẹnyin enia Judea, ati gbogbo ẹnyin ti ngbé Jerusalemu, ki eyiyi ki o yé nyin, ki ẹ si fetísi ọ̀rọ mi:

15. Nitori awọn wọnyi kò mutiyó, bi ẹnyin ti fi pè; wakati kẹta ọjọ sá li eyi.

16. Ṣugbọn eyi li ọ̀rọ ti a ti sọ lati ẹnu woli Joeli wá pe;

17. Ọlọrun wipe, Yio si ṣe ni ikẹhin ọjọ, Emi o tú ninu Ẹmí mi jade sara enia gbogbo: ati awọn ọmọ nyin-ọkunrin ati awọn ọmọ nyin obinrin yio ma sọtẹlẹ, awọn ọdọmọkunrin nyin yio si ma ri iran, awọn arugbo nyin yio si ma lá alá:

18. Ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi ọkunrin, ati sara awọn ọmọ-ọdọ mi obinrin li emi o tú ninu Ẹmí mi jade li ọjọ wọnni; nwọn o si ma sọtẹlẹ:

19. Emi o si fi iṣẹ iyanu hàn loke li ọrun, ati àmi nisalẹ lori ilẹ: ẹ̀jẹ, ati iná, ati ríru ẹ̃fin;

20. A o sọ õrùn di òkunkun, ati oṣupa di ẹ̀jẹ, ki ọjọ nla afiyesi Oluwa ki o to de:

Ka pipe ipin Iṣe Apo 2