Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 16:7-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nigbati nwọn de ọkankan Misia, nwọn gbé e wò lati lọ si Bitinia: ṣugbọn Ẹmí Jesu kò gbà fun wọn.

8. Nigbati nwọn si kọja lẹba Misia, nwọn sọkalẹ lọ si Troasi.

9. Iran kan si hàn si Paulu li oru: ọkunrin kan ara Makedonia duro, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Rekọja wá si Makedonia, ki o si ran wa lọwọ.

10. Nigbati o si ti ri iran na, lọgán awa mura lati lọ si Makedonia, a si gbà pe, Oluwa ti pè wa lati wasu ihinrere fun wọn.

11. Nitorina nigbati awa ṣikọ̀ ni Troasi a ba ọ̀na tàra lọ si Samotrakea, ni ijọ keji a si de Neapoli;

12. Lati ibẹ̀ awa si lọ si Filippi, ti iṣe ilu Makedonia, olu ilu ìha ibẹ, ilu labẹ Romani: awa si joko ni ilu yi fun ijọ melokan.

13. Lọjọ isimi, awa si jade lọ si ẹhin odi ilu na, lẹba odò kan, nibiti a rò pe ibi adura wà; awa si joko, a si ba awọn obinrin ti o pejọ sọrọ.

14. Ati obinrin kan ti orukọ rẹ̀ ijẹ Lidia, elesè àluko, ara ilu Tiatira, ẹniti o nsìn Ọlọrun, o gbọ́ ọ̀rọ wa: ọkàn ẹniti Oluwa ṣí, fetísi ohun ti a ti ẹnu Paulu sọ.

15. Nigbati a si baptisi rẹ̀, ati awọn ará ile rẹ̀, o bẹ̀ wa, wipe, Bi ẹnyin ba kà mi li olõtọ si Oluwa, ẹ wá si ile mi, ki ẹ si wọ̀ nibẹ̀. O si rọ̀ wa.

16. O si ṣe, bi awa ti nlọ si ibi adura na, ọmọbinrin kan ti o li ẹmi afọṣẹ, pade wa, ẹniti o fi afọṣẹ mu ère pipọ fun awọn oluwa rẹ̀ wá:

17. On na li o ntọ̀ Paulu ati awa lẹhin, o si nkigbe, wipe, Awọn ọkunrin wọnyi ni iranṣẹ Ọlọrun Ọgá-ogo, ti nkede ọ̀na igbala fun nyin.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 16