Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 14:13-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Alufa Jupiteri ti ile oriṣa rẹ̀ wà niwaju ilu wọn, si mu malu ati màriwo wá si ẹnubode, on iba si rubọ pẹlu awọn enia.

14. Ṣugbọn nigbati awọn aposteli Barnaba on Paulu gbọ́, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si sure wọ̀ inu awujọ, nwọn nke rara.

15. Nwọn si nwipe, Ará, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe nkan wọnyi? Enia oniru ìwa kanna bi ẹnyin li awa pẹlu ti a nwasu ihinrere fun nyin, ki ẹnyin ki o yipada kuro ninu ohun asan wọnyi si Ọlọrun alãye, ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn:

16. Ẹni, ni awọn iran ti o ti kọja jọwọ gbogbo orilẹ-ède, lati mã rìn li ọna tiwọn.

17. Ṣugbọn ko fi ara rẹ̀ silẹ li ailẹri, ni ti o nṣe rere, o nfun nyin ni òjo lati ọrun wá, ati akokò eso, o nfi onjẹ ati ayọ̀ kún ọkàn nyin.

18. Diẹ li o kù ki nwọn ki o ma le fi ọ̀rọ wọnyi da awọn enia duro, ki nwọn ki o máṣe rubọ bọ wọn.

19. Awọn Ju kan si ti Antioku ati Ikonioni wá, nigbati nwọn yi awọn enia li ọkàn pada, nwọn si sọ Paulu li okuta, nwọn wọ́ ọ jade kuro ni ilu na, nwọn ṣebi o kú.

20. Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin duro tì i yiká, o dide, o si wọ̀ ilu na lọ: ni ijọ keji o ba Barnaba lọ si Derbe.

21. Nigbati nwọn si ti wasu ihinrere fun ilu na, ti nwọn si ni ọmọ-ẹ̀hin pupọ, nwọn pada lọ si Listra, ati Ikonioni, ati si Antioku.

22. Nwọn nmu awọn ọmọ-ẹhin li ọkàn le, nwọn ngbà wọn niyanju lati duro ni igbagbọ́, ati pe ninu ipọnju pipọ li awa o fi wọ̀ ijọba Ọlọrun.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 14