Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 14:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, ni Ikonioni, nwọn jumọ wọ̀ inu sinagogu awọn Ju lọ, nwọn si sọrọ tobẹ̃, ti ọ̀pọlọpọ awọn Ju ati awọn Hellene gbagbọ́.

2. Ṣugbọn awọn alaigbagbọ́ Ju rú ọkàn awọn Keferi soke, nwọn si rọ̀ wọn si awọn arakunrin na.

3. Nitorina nwọn gbe ibẹ̀ pẹ, nwọn nfi igboiya sọrọ ninu Oluwa, ẹniti o jẹri si ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, o si nyọnda ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu mã ti ọwọ́ wọn ṣe.

4. Ṣugbọn ọ̀pọ enia ilu na pin meji: apakan si dàpọ mọ́ awọn Ju, apakan si dàpọ mọ́ awọn aposteli.

5. Bi awọn Keferi, ati awọn Ju pẹlu awọn olori wọn ti fẹ kọlù wọn lati ṣe àbuku si wọn, ati lati sọ wọn li okuta,

6. Nwọn mọ̀, nwọn si sá lọ si Listra ati Derbe ilu Likaonia, ati si àgbegbe ti o yiká:

7. Nibẹ̀ ni nwọn si nwasu ihinrere.

8. Ọkunrin kan si joko ni Listra, ẹniti ẹsẹ rẹ̀ kò mokun, arọ lati inu iya rẹ̀ wá, ti kò rìn ri.

9. Ọkunrin yi gbọ́ bi Paulu ti nsọ̀rọ: ẹni, nigbati o tẹjumọ́ ọ, ti o si ri pe, o ni igbagbọ́ fun imularada,

10. O wi fun u li ohùn rara pe, Dide duro ṣanṣan li ẹsẹ rẹ. O si nfò soke o si nrìn.

11. Nigbati awọn enia si ri ohun ti Paulu ṣe, nwọn gbé ohùn wọn soke li ède Likaonia, wipe, Awọn oriṣa sọkalẹ tọ̀ wa wá ni àwọ enia.

12. Nwọn si pè Barnaba ni Jupiteri ati Paulu ni Herme nitori on li olori ọ̀rọ isọ.

13. Alufa Jupiteri ti ile oriṣa rẹ̀ wà niwaju ilu wọn, si mu malu ati màriwo wá si ẹnubode, on iba si rubọ pẹlu awọn enia.

14. Ṣugbọn nigbati awọn aposteli Barnaba on Paulu gbọ́, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si sure wọ̀ inu awujọ, nwọn nke rara.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 14