Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Tim 6:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. KI gbogbo awọn ti iṣe ẹrú labẹ ìrú mã ka awọn oluwa ti o ni wọn yẹ si ọla gbogbo, ki a má bã sọrọ-odi si orukọ Ọlọrun ati ẹkọ́ rẹ̀.

2. Awọn ti o si ni oluwa onigbagbọ́, ki nwọn máṣe gàn wọn nitori arakunrin ni nwọn; ṣugbọn ki nwọn tubọ mã sìn wọn, nitori awọn ti iṣe alabapin iṣẹ rere wọn jẹ onigbagbọ́ ati olufẹ. Nkan wọnyi ni ki o mã kọ́ni ki o si mã fi gba-ni-niyanju.

3. Bi ẹnikẹni ba nkọ́ni li ẹkọ miran, ti kò si gba ọ̀rọ ti o ye kõro, ani ọ̀rọ Jesu Kristi Oluwa wa, ati ẹkọ́ gẹgẹ bi ìwa-bi-Ọlọrun.

4. O gberaga, kò mọ nkan kan, bikoṣe ifẹ iyan-jija ati ìja-ọ̀rọ ninu eyiti ilara, ìya, ọrọ buburu ati iro buburu ti iwá,

5. Ọ̀rọ̀ ayipo awọn enia ọlọkan ẽri ti kò si otitọ ninu wọn, ti nwọn ṣebi ọna si ere ni ìwa-bi-Ọlọrun: yẹra lọdọ irú awọn wọnni.

Ka pipe ipin 1. Tim 6