Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Tim 3:8-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Bẹ̃ gẹgẹ li o yẹ fun awọn diakoni lati ni ìwa àgba, ki nwọn má jẹ ẹlẹnu meji, kì nwọn má fi ara wọn fun waini pupọ̀, ki nwọn má jẹ olojukokoro.

9. Ki nwọn mã di ohun ijinlẹ igbagbọ́ mu li ọkàn funfun.

10. Ki a si kọ́ wá idi awọn wọnyi daju pẹlu; nigbana ni ki a jẹ ki nwọn jẹ oyè diakoni, bi nwọn ba jẹ alailẹgan.

11. Bẹ̃ gẹgẹ li o yẹ fun awọn obinrin lati ni iwa àgba, kì nwọn má jẹ asọrọ-ẹni-lẹhin bikoṣe alairekọja, olõtọ li ohun gbogbo.

12. Ki awọn diakoni jẹ ọkọ obinrin kan, ki nwọn ki o káwọ awọn ọmọ wọn ati ile ara wọn daradara.

13. Nitori awọn ti o lò oyè diakoni daradara rà ipo rere fun ara wọn, ati igboiya pupọ ni igbagbọ́ ti mbẹ ninu Kristi Jesu.

14. Iwe nkan wọnyi ni mo kọ si ọ, mo si nreti ati tọ̀ ọ wá ni lọ̃lọ̃.

15. Ṣugbọn bi mo ba pẹ, ki iwọ ki o le mọ̀ bi o ti yẹ fun awọn enia lati mã huwa ninu ile Ọlọrun, ti iṣe ijọ Ọlọrun alãye, ọwọ̀n ati ipilẹ otitọ.

16. Laiṣiyemeji, titobi ni ohun ijinlẹ ìwa-bi-Ọlọrun, ẹniti a fihan ninu ara, ti a dalare ninu Ẹmí, ti awọn angẹli ri, ti a wasu rẹ̀ lãrin awọn orilẹ-ede, ti a gbagbọ ninu aiye, ti a gba soke sinu ogo.

Ka pipe ipin 1. Tim 3