Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Tes 4:10-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nitõtọ ẹnyin si nṣe e si gbogbo awọn ará ti o wà ni gbogbo Makedonia: ṣugbọn awa mbẹ̀ nyin, ará, pe ki ẹnyin ki o mã pọ̀ siwaju si i;

11. Ati pe ki ẹnyin ki o mã dù u gidigidi lati gbé jẹ, lati mã gbọ ti ara nyin, ki ẹ mã fi ọwọ́ nyin ṣiṣẹ, gẹgẹ bi awa ti paṣẹ fun nyin;

12. Ki ẹnyin ki o le mã rìn ìrin ẹ̀tọ́ si awọn ti mbẹ lode, ki ẹ le má ṣe alaini ohunkohun.

13. Ṣugbọn awa kò fẹ ki ẹnyin ki o jẹ òpe, ará, niti awọn ti o sùn, pe ki ẹ má binujẹ gẹgẹ bi awọn iyoku ti kò ni ireti.

14. Nitori bi awa ba gbagbọ́ pe Jesu ti kú, o si ti jinde, gẹgẹ bẹ̃ni Ọlọrun yio mu awọn ti o sùn pẹlu ninu Jesu wá pẹlu ara rẹ̀.

15. Nitori eyiyi li awa nwi fun nyin nipa ọ̀rọ Oluwa, pe awa ti o wà lãye, ti a si kù lẹhin de atiwá Oluwa, bi o ti wu ki o ri kì yio ṣaju awọn ti o sùn.

16. Nitori Oluwa tikararẹ̀ yio sọkalẹ lati ọrun wá ti on ti ariwo, pẹlu ohùn olori awọn angẹli, ati pẹlu ipè Ọlọrun; awọn okú ninu Kristi ni yio si kọ́ jinde:

17. Nigbana li a ó si gbà awa ti o wà lãye ti o si kù lẹhin soke pẹlu wọn sinu awọsanma, lati pade Oluwa li oju ọrun: bẹ̃li awa ó si ma wà titi lai lọdọ Oluwa.

18. Nitorina, ẹ mã fi ọ̀rọ wọnyi tu ara nyin ninu.

Ka pipe ipin 1. Tes 4