Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Tes 2:8-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Bẹ̃ gẹgẹ bi awa ti ni ifẹ inu rere si nyin, inu wa dun jọjọ lati fun nyin kì iṣe ihinrere Ọlọrun nikan, ṣugbọn ẹmí awa tikarawa pẹlu, nitoriti ẹnyin jẹ ẹni ọ̀wọ́n fun wa.

9. Nitori ẹnyin ranti, ará, ìṣẹ́ ati lãlã wa: nitori awa nṣe lãlã li ọsán ati li oru, ki awa ko má bã di ẹrù ru ẹnikẹni ninu nyin, awa wasu ihinrere Ọlọrun fun nyin.

10. Ẹnyin si li ẹlẹri, ati Ọlọrun pẹlu, bi awa ti wà lãrin ẹnyin ti o gbagbọ́ ni mimọ́ iwà ati li ododo, ati li ailẹgan:

11. Gẹgẹ bi ẹnyin si ti mọ̀ bi awa ti mba olukuluku nyin lo gẹgẹ bi baba si awọn ọmọ rẹ̀, a ngba nyin niyanju, a ntu nyin ninu, a si kọ́,

12. Ki ẹnyin ki o le mã rìn ni yiyẹ Ọlọrun, ẹniti o npè nyin sinu ijọba ati ogo On tikararẹ.

13. Nitori eyi li awa ṣe ndupẹ lọwọ Ọlọrun pẹlu li aisimi, pe nigbati ẹnyin gba ọ̀rọ ti ẹnyin gbọ lọdọ wa, ani ọ̀rọ Ọlọrun, ẹnyin kò gbà a bi ẹnipe ọ̀rọ enia, ṣugbọn gẹgẹ bi o ti jẹ nitõtọ, bi ọ̀rọ Ọlọrun, eyiti o ṣiṣẹ gidigidi ninu ẹnyin ti o gbagbọ́ pẹlu.

14. Nitori, ará, ẹnyin di alafarawe awọn ijọ Ọlọrun ti mbẹ ni Judea, ninu Kristi Jesu: nitoripe ẹnyin pẹlu jìya iru ohun kanna lọwọ awọn ara ilu nyin, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti jìya lọwọ awọn Ju:

15. Awọn ẹniti o pa Jesu Oluwa, ati awọn woli, nwọn si tì wa jade; nwọn kò si ṣe eyiti o wu Ọlọrun, nwọn si wà lodi si gbogbo enia:

16. Nwọn kọ̀ fun wa lati sọ̀rọ fun awọn Keferi ki nwọn ki o le là, lati mã sọ ẹ̀ṣẹ wọn di kikun nigbagbogbo: ṣugbọn ibinu de bá wọn titi de opin.

Ka pipe ipin 1. Tes 2