Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Pet 5:2-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ẹ mã tọju agbo Ọlọrun ti mbẹ lãrin nyin, ẹ mã bojuto o, kì iṣe afipáṣe, bikoṣe tifẹtifẹ; bẹni ki iṣe ọrọ ère ijẹkujẹ, ṣugbọn pẹlu ọkàn ti o mura tan.

3. Bẹ̃ni ki iṣe bi ẹniti nlo agbara lori ijọ, ṣugbọn ki ẹ ṣe ara nyin li apẹrẹ fun agbo.

4. Nigbati olori Oluṣọ-agutan ba si fi ara hàn, ẹnyin ó gbà ade ogo ti kì iṣá.

5. Bẹ̃ pẹlu, ẹnyin ipẹ̃rẹ, ẹ tẹriba fun awọn àgba. Ani, gbogbo nyin, ẹ mã tẹriba fun ara nyin, ki ẹ si fi irẹlẹ wọ̀ ara nyin li aṣọ: nitori Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn O nfi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ.

6. Nitorina ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ labẹ ọwọ́ agbara Ọlọrun, ki on ki o le gbé nyin ga li akokò.

7. Ẹ mã kó gbogbo aniyan nyin le e; nitoriti on nṣe itọju nyin.

8. Ẹ mã wà li airekọja, ẹ mã ṣọra; nitori Èṣu, ọtá nyin, bi kiniun ti nke ramuramu, o nrìn kãkiri, o nwá ẹniti yio pajẹ kiri:

9. Ẹniti ki ẹnyin ki o kọ oju ija si pẹlu iduroṣinṣin ninu igbagbọ́, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe ìya kanna ni awọn ara nyin ti mbẹ ninu aiye njẹ.

Ka pipe ipin 1. Pet 5