Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 7:13-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ati obinrin ti o ni ọkọ ti kò gbagbọ́, bi inu rẹ̀ ba si dùn lati mã ba a gbé, ki on máṣe fi i silẹ.

14. Nitoriti a sọ alaigbagbọ́ ọkọ na di mimọ́ ninu aya rẹ̀, a si sọ alaigbagbọ́ aya na di mimọ́ ninu ọkọ rẹ̀: bikoṣe bẹ̃ awọn ọmọ nyin iba jẹ alaimọ́; ṣugbọn nisisiyi nwọn di mimọ́.

15. Ṣugbọn bi alaigbagbọ́ na ba lọ, jẹ ki o mã lọ. Arakunrin tabi arabinrin kan kò si labẹ ìde, nitori irú ọ̀ran bawọnni: ṣugbọn Ọlọrun pè wa si alafia.

16. Nitori iwọ ti ṣe mọ̀, iwọ aya, bi iwọ ó gbà ọkọ rẹ là? tabi iwọ ti ṣe mọ̀, iwọ ọkọ, bi iwọ ó gbà aya rẹ là?

17. Ṣugbọn gẹgẹ bi Ọlọrun ti pín fun olukuluku enia, bi Oluwa ti pè olukuluku, bẹ̃ni ki o si mã rìn. Bẹ̃ni mo si nṣe ìlana ninu gbogbo ijọ.

18. A ha pè ẹnikan ti o ti kọla? ki o má si ṣe di alaikọla. A ha pè ẹnikan ti kò kọla? ki o máṣe kọla.

19. Ikọla ko jẹ nkan, ati aikọla kò jẹ nkan, bikoṣe pipa ofin Ọlọrun mọ́.

20. Ki olukuluku enia duro ninu ìpe nipasẹ eyi ti a ti pè e.

21. A ha pè ọ, nigbati iwọ jẹ ẹrú? máṣe kà a si: ṣugbọn bi iwọ ba le di omnira, kuku ṣe eyini.

22. Nitori ẹniti a pè ninu Oluwa, ti iṣe ẹrú, o di ẹni omnira ti Oluwa: gẹgẹ bẹ̃ li ẹniti a pè ti o jẹ omnira, o di ẹrú Kristi.

23. A ti rà nyin ni iye kan; ẹ máṣe di ẹrú enia.

24. Ará, ki olukuluku enia, ninu eyi ti a pè e, ki o duro ninu ọkanna pẹlu Ọlọrun.

25. Ṣugbọn nipa ti awọn wundia, emi kò ni aṣẹ Oluwa: ṣugbọn mo fun nyin ni imọran bi ẹniti o ri ãnu Oluwa gbà lati jẹ olododo.

26. Nitorina mo rò pe eyi dara nitori wahalà isisiyi, eyini ni pe, o dara fun enia ki o wà bẹ̃.

27. A ti dè ọ mọ́ aya ri bi? máṣe wá ọ̀na lati tú kuro. A ti tú ọ kuro lọwọ aya bi? máṣe wá aya ni.

Ka pipe ipin 1. Kor 7