Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 5:8-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Nitorina ẹ jẹ ki a ṣe ajọ na, kì iṣe pẹlu iwukara atijọ, bẹ̃ni ki iṣe pẹlu iwukara arankàn ati ìwa buburu; bikoṣe pẹlu aiwukara ododo ati otitọ.

9. Emi ti kọwe si nyin ninu iwe mi pe, ki ẹ máṣe ba awọn àgbere kẹgbẹ pọ̀:

10. Ṣugbọn kì iṣe pẹlu awọn àgbere aiye yi patapata, tabi pẹlu awọn olojukòkoro, tabi awọn alọnilọwọgbà, tabi awọn abọriṣa; nitori nigbana ẹ kò le ṣaima ti aiye kuro.

11. Ṣugbọn nisisiyi mo kọwe si nyin pe, bi ẹnikẹni ti a npè ni arakunrin ba jẹ àgbere, tabi olojukòkoro, tabi abọriṣa, tabi ẹlẹgàn, tabi ọmutipara, tabi alọnilọwọgbà; ki ẹ máṣe ba a kẹgbẹ; irú ẹni bẹ̃ ki ẹ má tilẹ ba a jẹun.

12. Nitori ewo ni temi lati mã ṣe idajọ awọn ti mbẹ lode? ki ha ṣe awọn ti o wà ninu li ẹnyin ṣe idajọ wọn?

13. Ṣugbọn awọn ti o wà lode li Ọlọrun nṣe idajọ wọn. Ẹ yọ enia buburu na kuro larin ara nyin.

Ka pipe ipin 1. Kor 5