4. Li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa. Nigbati ẹnyin ba pejọ, ati ẹmí mi, pẹlu agbara Jesu Kristi Oluwa wa,
5. Ki ẹ fi irú enia bẹ̃ le Satani lọwọ fun iparun ara, ki a le gbà ẹmí là li ọjọ Jesu Oluwa.
6. Iṣeféfe nyin kò dara. Ẹnyin kò mọ̀ pe iwukara diẹ ni imu gbogbo iyẹfun di wiwu?
7. Nitorina ẹ mu iwukara atijọ kuro ninu nyin, ki ẹnyin ki o le jẹ́ iyẹfun titun, gẹgẹ bi ẹnyin ti jẹ́ aiwukara. Nitori a ti fi irekọja wa, ani Kristi, rubọ fun wa.
8. Nitorina ẹ jẹ ki a ṣe ajọ na, kì iṣe pẹlu iwukara atijọ, bẹ̃ni ki iṣe pẹlu iwukara arankàn ati ìwa buburu; bikoṣe pẹlu aiwukara ododo ati otitọ.
9. Emi ti kọwe si nyin ninu iwe mi pe, ki ẹ máṣe ba awọn àgbere kẹgbẹ pọ̀:
10. Ṣugbọn kì iṣe pẹlu awọn àgbere aiye yi patapata, tabi pẹlu awọn olojukòkoro, tabi awọn alọnilọwọgbà, tabi awọn abọriṣa; nitori nigbana ẹ kò le ṣaima ti aiye kuro.
11. Ṣugbọn nisisiyi mo kọwe si nyin pe, bi ẹnikẹni ti a npè ni arakunrin ba jẹ àgbere, tabi olojukòkoro, tabi abọriṣa, tabi ẹlẹgàn, tabi ọmutipara, tabi alọnilọwọgbà; ki ẹ máṣe ba a kẹgbẹ; irú ẹni bẹ̃ ki ẹ má tilẹ ba a jẹun.
12. Nitori ewo ni temi lati mã ṣe idajọ awọn ti mbẹ lode? ki ha ṣe awọn ti o wà ninu li ẹnyin ṣe idajọ wọn?
13. Ṣugbọn awọn ti o wà lode li Ọlọrun nṣe idajọ wọn. Ẹ yọ enia buburu na kuro larin ara nyin.