Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 15:46-58 Yorùbá Bibeli (YCE)

46. Ṣugbọn eyi ti iṣe ẹlẹmí kọ́ tète ṣaju, bikoṣe eyi ti iṣe ara iyara; lẹhinna eyi ti iṣe ẹlẹmí.

47. Ọkunrin iṣaju ti inu erupẹ̀ wá, ẹni erupẹ̀: ọkunrin ekeji Oluwa lati ọrun wá ni.

48. Bi ẹni erupẹ̀ ti ri, irú bẹ̃ si ni awọn ti iṣe ti erupẹ̀: bi ẹni ti ọrun ti ri, irú bẹ si ni awọn ti iṣe ti ọrun.

49. Bi awa si ti rù aworan ẹni erupẹ̀, bẹ̃li awa ó si ru aworan ẹni ti ọrun.

50. Ará, njẹ eyi ni mo wipe, ara on ẹ̀jẹ kò le jogún ijọba Ọlọrun; bẹ̃ni idibajẹ kò le jogún aidibajẹ.

51. Kiyesi i, ohun ijinlẹ ni mo sọ fun nyin; gbogbo wa kì yio sùn, ṣugbọn gbogbo wa li a o palarada,

52. Lọgan, ni iṣẹ́ju, nigba ipè ikẹhin: nitori ipè yio dún, a o si jí awọn okú dide li aidibajẹ, a ó si pawalara dà.

53. Nitoripe ara idibajẹ yi kò le ṣaigbé aidibajẹ wọ̀, ati ara kikú yi kò le ṣaigbé ara aiku wọ̀.

54. Ṣugbọn nigbati ara idibajẹ yi ba ti gbe aidibajẹ wọ̀, ti ara kikú yi ba si ti gbe aikú wọ̀ bẹ̃ tan, nigbana ni ọ̀rọ ti a kọ yio ṣẹ pe, A gbé ikú mì ni iṣẹgun.

55. Ikú, oró rẹ dà? Isà okú, iṣẹgun rẹ dà?

56. Oró ikú li ẹ̀ṣẹ; ati agbara ẹ̀ṣẹ li ofin.

57. Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun ẹniti o fi iṣẹgun fun wa nipa Oluwa wa Jesu Kristi.

58. Nitorina ẹnyin ará mi olufẹ ẹ mã duro ṣinṣin, laiyẹsẹ, ki ẹ mã pọ̀ si i ni iṣẹ Oluwa nigbagbogbo, niwọn bi ẹnyin ti mọ̀ pe iṣẹ nyin kì iṣe asan ninu Oluwa.

Ka pipe ipin 1. Kor 15