Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 15:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ, ará, emi nsọ ihinrere na di mimọ̀ fun nyin ti mo ti wãsu fun nyin, eyiti ẹnyin pẹlu ti gbà, ninu eyi ti ẹnyin si duro;

2. Nipaṣe eyiti a fi ngbà nyin là pẹlu, bi ẹnyin ba di ọ̀rọ ti mo ti wãsu fun nyin mú ṣinṣin, bikoṣepe ẹnyin ba gbagbọ́ lasan.

3. Nitoripe ṣiwaju ohun gbogbo mo fi eyiti emi pẹlu ti gbà le nyin lọwọ, bi Kristi ti kú nitori ẹ̀ṣẹ wa gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi;

4. Ati pe a sinkú rẹ̀, ati pe o jinde ni ijọ kẹta gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi:

5. Ati pe o farahan Kefa, lẹhin eyini awọn mejila:

6. Lẹhin eyini o farahan awọn ará ti o jù ẹ̃dẹgbẹta lọ lẹkanna; apakan ti o pọ̀ju ninu wọn wà titi fi di isisiyi, ṣugbọn awọn diẹ ti sùn.

7. Lẹhin eyini o farahan Jakọbu; lẹhinna fun gbogbo awọn Aposteli.

8. Ati nikẹhin gbogbo wọn o farahàn mi pẹlu, bi ẹni ti a bí ṣiwaju akokò rẹ̀.

9. Nitori emi li ẹniti o kere jùlọ ninu awọn Aposteli, emi ẹniti kò yẹ ti a ba pè li Aposteli, nitoriti mo ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun.

10. Ṣugbọn nipa õre-ọfẹ Ọlọrun, mo ri bi mo ti ri: õre-ọfẹ rẹ̀ ti a fifun mi kò si jẹ asan; ṣugbọn mo ṣiṣẹ lọpọlọpọ jù gbogbo wọn lọ: ṣugbọn kì iṣe emi, bikoṣe õre-ọfẹ Ọlọrun ti o wà pẹlu mi.

11. Nitorina ibã ṣe emi tabi awọn ni, bẹ̃li awa wãsu, bẹ̃li ẹnyin si gbagbọ́.

12. Njẹ bi a ba nwasu Kristi pe o ti jinde kuro ninu okú, ẽhatiṣe ti awọn miran ninu nyin fi wipe, ajinde okú kò si?

Ka pipe ipin 1. Kor 15