Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 14:21-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. A ti kọ ọ ninu ofin pe, Nipa awọn alahọn miran ati elete miran li emi ó fi bá awọn enia yi sọrọ; sibẹ nwọn kì yio gbọ temi, li Oluwa wi.

22. Nitorina awọn ahọn jasi àmi kan, kì iṣe fun awọn ti o gbagbọ́, bikoṣe fun awọn alaigbagbọ́: ṣugbọn isọtẹlẹ kì iṣe fun awọn ti kò gbagbọ́, bikoṣe fun awọn ti o gbagbọ́.

23. Njẹ bi gbogbo ijọ ba pejọ si ibi kan, ti gbogbo nwọn si nfi ède fọ̀, bi awọn ti iṣe alailẹkọ́ ati alaigbagbọ́ ba wọle wá, nwọn kì yio ha wipe ẹnyin nṣe wère?

24. Ṣugbọn bi gbogbo nyin ba nsọtẹlẹ, ti ẹnikan ti kò gbagbọ́ tabi ti kò li ẹ̀kọ́ bá wọle wá, gbogbo nyin ni yio fi òye ẹ̀ṣẹ yé e, gbogbo nyin ni yio wadi rẹ̀:

25. Bẹ̃li a si fi aṣiri ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ̃li on o si dojubolẹ yio si sin Ọlọrun, yio si sọ pe, nitotọ Ọlọrun mbẹ larin nyin.

26. Njẹ ẽhatiṣe, ará? nigbati ẹnyin pejọ pọ̀, ti olukuluku nyin ni psalmu kan, ẹkọ́ kan, ède kan, ifihàn kan, itumọ̀ kan. Ẹ mã ṣe ohun gbogbo lati gbe-ni-ro.

27. Bi ẹnikan ba fi ède fọ̀, ki o jẹ enia meji, tabi bi o pọ̀ tan, ki o jẹ mẹta, ati eyini li ọkọ̃kan; si jẹ ki ẹnikan gbufọ.

28. Ṣugbọn bi kò ba si ogbufọ, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́ ninu ijọ; si jẹ ki o mã bá ara rẹ̀ ati Ọlọrun sọrọ.

Ka pipe ipin 1. Kor 14