Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kor 1:4-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigbagbogbo nitori nyin, nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun nyin ninu Jesu Kristi;

5. Nitoripe nipasẹ rẹ̀ li a ti sọ nyin di ọlọrọ̀ li ohun gbogbo, ninu ọ̀rọ-isọ gbogbo, ati ninu ìmọ gbogbo;

6. Ani gẹgẹ bi a ti fi idi ẹrí Kristi kalẹ ninu nyin:

7. Tobẹ ti ẹnyin kò fi rẹ̀hin ninu ẹ̀bunkẹbun; ti ẹ si nreti ifarahàn Oluwa wa Jesu Kristi:

8. Ẹniti yio si fi idi nyin kalẹ titi de opin, ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn li ọjọ Oluwa wa Jesu Kristi.

9. Olododo li Ọlọrun, nipasẹ ẹniti a pè nyin sinu ìdapọ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa.

10. Mo si bẹ̀ nyin, ará, li orukọ Oluwa wa Jesu Kristi, ki gbogbo nyin mã sọ̀rọ ohun kanna, ati ki ìyapa ki o máṣe si ninu nyin; ṣugbọn ki a le ṣe nyin pé ni inu kanna, ati ni ìmọ kanna.

11. Nitori a ti fihàn mi nipa tinyin, ará mi, lati ọdọ awọn ara ile Kloe, pe ìja mbẹ larin nyin.

12. Njẹ eyi ni mo wipe, olukuluku nyin nwipe, Emi ni ti Paulu; ati emi ni ti Apollo; ati emi ni ti Kefa; ati emi ni ti Kristi.

13. A ha pin Kristi bi? iṣe Paulu li a kàn mọ agbelebu fun nyin bi? tabi li orukọ Paulu li a baptisi nyin si?

14. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe emi kò baptisi ẹnikẹni ninu nyin, bikoṣe Krispu ati Gaiu;

15. Ki ẹnikẹni ki o máṣe wipe mo ti mbaptisi li orukọ emi tikarami.

16. Mo si baptisi awọn ara ile Stefana pẹlu: lẹhin eyi emi kò mọ̀ bi mo ba baptisi ẹlomiran pẹlu.

17. Nitori Kristi kò rán mi lọ ibaptisi, bikoṣe lati wãsu ihinrere: kì iṣe nipa ọgbọ́n ọ̀rọ, ki a máṣe sọ agbelebu Kristi di alailagbara.

18. Nitoripe wère li ọ̀rọ agbelebu si awọn ti o nṣegbé; ṣugbọn si awa ti a ngbalà, agbara Ọlọrun ni.

19. Nitoriti a kọ ọ pe, Emi ó pa ọgbọ́n awọn ọlọ́gbọn run, emi ó si sọ òye awọn olóye di asan.

Ka pipe ipin 1. Kor 1