Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Joh 3:3-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Olukuluku ẹniti o ba si ni ireti yi ninu rẹ̀, a wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ani bi on ti mọ́.

4. Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ o nrú ofin pẹlu: nitori ẹ̀ṣẹ ni riru ofin.

5. Ẹnyin si mọ̀ pe, on farahàn lati mu ẹ̀ṣẹ kuro; ẹ̀ṣẹ kò si si ninu rẹ̀.

6. Ẹnikẹni ti o ba ngbé inu rẹ̀ ki idẹṣẹ; ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ kò ri i, bẹ̃ni kò mọ̀ ọ.

7. Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o tàn nyin: ẹniti o ba nṣe ododo, o jasi olododo, gẹgẹ bi on ti iṣe olododo.

8. Ẹniti o ba ndẹṣẹ ti Èṣu ni; nitori lati àtetekọṣe ni Èṣu ti ndẹṣẹ. Nitori eyi li Ọmọ Ọlọrun ṣe farahàn, ki o le pa iṣẹ Èṣu run.

9. Ẹnikẹni ti a ti ipa Ọlọrun bí, ki idẹṣẹ; nitoriti irú rẹ̀ ngbe inu rẹ̀: kò si le dẹṣẹ nitoripe a ti ti ipa Ọlọrun bi i.

10. Ninu eyi li awọn ọmọ Ọlọrun nfarahan, ati awọn ọmọ Èṣu: ẹnikẹni ti kò ba nṣe ododo kì iṣe ti Ọlọrun, ati ẹniti kò fẹràn arakunrin rẹ̀.

11. Nitori eyi ni iṣẹ ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe, ki awa ki o fẹràn ara wa.

12. Ki iṣe bi Kaini, ti jẹ́ ti ẹni buburu nì, ti o si pa arakunrin rẹ̀. Nitori kili o si ṣe pa a? Nitoriti iṣẹ on jẹ buburu, ti arakunrin rẹ̀ si jẹ ododo.

13. Ki ẹnu ki o máṣe yà nyin, ẹnyin ará mi, bi aiye ba korira nyin.

Ka pipe ipin 1. Joh 3