Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Joh 3:17-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ṣugbọn ẹniti o ba ni ohun ini aiye, ti o si ri arakunrin rẹ̀ ti iṣe alaini, ti o si sé ilẹkun ìyọ́nu rẹ̀ mọ ọ, bawo ni ifẹ Ọlọrun ti ngbé inu rẹ̀?

18. Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ ki a fi ọrọ tabi ahọn fẹran, bikoṣe ni iṣe ati li otitọ.

19. Ati nipa eyi li awa ó mọ̀ pe awa jẹ ti otitọ, ati pe awa o si dá ara wa loju niwaju rẹ̀,

20. Ninu ohunkohun ti ọkàn wa ba ndá wa lẹbi; nitoripe Ọlọrun tobi jù ọkàn wa lọ, o si mọ̀ ohun gbogbo.

21. Olufẹ, bi ọkàn wa kò ba dá wa lẹbi, njẹ awa ni igboiya niwaju Ọlọrun.

22. Ati ohunkohun ti awa ba bère, awa nri gbà lọdọ rẹ̀, nitoriti awa npa ofin rẹ̀ mọ́, awa si nṣe nkan wọnni ti o dara loju rẹ̀.

23. Eyi si li ofin rẹ̀, pe ki awa ki o gbà orukọ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ gbọ́, ki a si fẹràn ara wa, gẹgẹ bi o ti fi ofin fun wa.

Ka pipe ipin 1. Joh 3