Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heb 1:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN, ẹni, ni igba pupọ̀ ati li onirũru ọna, ti o ti ipa awọn woli ba awọn baba sọ̀rọ nigbãni.

2. Ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ Ọmọ rẹ̀ ba wa sọ̀rọ, ẹniti o fi ṣe ajogun ohun gbogbo, nipasẹ ẹniti o dá awọn aiye pẹlu;

3. Ẹniti iṣe itanṣan ogo rẹ̀, ati aworan on tikararẹ, ti o si nfi ọ̀rọ agbara rẹ̀ mu ohun gbogbo duro, lẹhin ti o ti ṣe ìwẹnu ẹ̀ṣẹ, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlánla li oke;

4. O si ti fi bẹ̃ di ẹniti o sàn ju awọn angẹli lọ, bi o ti jogun orukọ ti o ta tiwọn yọ.

5. Nitori ewo ninu awọn angẹli li o wi fun rí pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ? Ati pẹlu, Emi yio jẹ Baba fun u, on yio si jẹ Ọmọ fun mi?

6. Ati pẹlu, nigbati o mu akọbi ni wá si aiye, o wipe, Ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun ki o foribalẹ fun u.

Ka pipe ipin Heb 1