orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Heb 1 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ọlọrun Sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ Rẹ̀

1. ỌLỌRUN, ẹni, ni igba pupọ̀ ati li onirũru ọna, ti o ti ipa awọn woli ba awọn baba sọ̀rọ nigbãni.

2. Ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ Ọmọ rẹ̀ ba wa sọ̀rọ, ẹniti o fi ṣe ajogun ohun gbogbo, nipasẹ ẹniti o dá awọn aiye pẹlu;

3. Ẹniti iṣe itanṣan ogo rẹ̀, ati aworan on tikararẹ, ti o si nfi ọ̀rọ agbara rẹ̀ mu ohun gbogbo duro, lẹhin ti o ti ṣe ìwẹnu ẹ̀ṣẹ, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlánla li oke;

Ọmọ Ọlọrun ju àwọn Angẹli lọ

4. O si ti fi bẹ̃ di ẹniti o sàn ju awọn angẹli lọ, bi o ti jogun orukọ ti o ta tiwọn yọ.

5. Nitori ewo ninu awọn angẹli li o wi fun rí pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ? Ati pẹlu, Emi yio jẹ Baba fun u, on yio si jẹ Ọmọ fun mi?

6. Ati pẹlu, nigbati o mu akọbi ni wá si aiye, o wipe, Ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun ki o foribalẹ fun u.

7. Ati niti awọn angẹli, o wipe, Ẹniti o dá awọn angẹli rẹ̀ li ẹmí, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ li ọwọ́ iná.

8. Ṣugbọn niti Ọmọ li o wipe, Itẹ́ rẹ, Ọlọrun, lai ati lailai ni; ọpá alade ododo li ọpá alade ijọba rẹ.

9. Iwọ fẹ ododo, iwọ si korira ẹ̀ṣẹ; nitorina li Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ, ṣe fi oróro ayọ̀ yan ọ jù awọn ẹgbẹ rẹ lọ.

10. Ati Iwọ, Oluwa, li atetekọṣe li o ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; awọn ọrun si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ:

11. Nwọn ó ṣegbe; ṣugbọn iwọ ó wà sibẹ, gbogbo wọn ni yio si gbó bi ẹwu;

12. Ati bi aṣọ ni iwọ o si ká wọn, a o si pàrọ wọn: ṣugbọn bakanna ni iwọ, ọdún rẹ kì yio si pin.

13. Ṣugbọn ewo ninu awọn angẹli li o sọ nipa rẹ̀ ri pe, Joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ?

14. Ẹmí ti njiṣẹ ki gbogbo wọn iṣe, ti a nran lọ lati mã jọsin nitori awọn ti yio jogun igbala?