Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gal 3:12-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ofin kì si iṣe ti igbagbọ́: ṣugbọn Ẹniti nṣe wọn yio yè nipasẹ wọn.

13. Kristi ti rà wa pada kuro lọwọ egun ofin, ẹniti a fi ṣe egun fun wa: nitoriti a ti kọ ọ pe, Ifibu li olukuluku ẹniti a fi kọ́ sori igi:

14. Ki ibukún Abrahamu ki o le wá sori awọn Keferi nipa Kristi Jesu; ki awa ki o le gbà ileri Ẹmí nipa igbagbọ́.

15. Ará, emi nsọ̀rọ bi enia; bi o tilẹ jẹ pe majẹmu enia ni, ṣugbọn bi a ba ti fi idi rẹ̀ mulẹ, kò si ẹniti o le sọ ọ di asan, tabi ti o le fi kún u mọ́.

16. Njẹ fun Abrahamu ati fun irú-ọmọ rẹ̀ li a ti ṣe awọn ileri na. On kò wipe, Fun awọn irú ọmọ, bi ẹnipe ọ̀pọlọpọ; ṣugbọn bi ẹnipe ọ̀kan, ati fun irú-ọmọ rẹ, eyiti iṣe Kristi.

17. Eyi ni mo nwipe, majẹmu ti Ọlọrun ti fi idi rẹ̀ mulẹ niṣãju, ofin ti o de lẹhin ọgbọ̀n-le-nirinwo ọdún kò le sọ ọ di asan, ti a ba fi mu ileri na di alailagbara.

18. Nitori bi ijogun na ba ṣe ti ofin, kì iṣe ti ileri mọ́: ṣugbọn Ọlọrun ti fi i fun Abrahamu nipa ileri.

19. Njẹ ki ha li ofin? a fi kun u nitori irekọja titi irú-ọmọ ti a ti ṣe ileri fun yio fi de; a si ti ipasẹ awọn angẹli ṣe ìlana rẹ̀ lati ọwọ́ alarina kan wá.

20. Njẹ alarina kì iṣe alarina ti ẹnikan, ṣugbọn ọ̀kan li Ọlọrun.

21. Nitorina ofin ha lodi si awọn ileri Ọlọrun bi? Ki a má ri: nitori ibaṣepe a ti fi ofin kan funni, ti o lagbara lati sọni di ãye, nitotọ ododo iba ti ti ipasẹ ofin wá.

22. Ṣugbọn iwe-mimọ́ ti sé gbogbo nkan mọ́ sabẹ ẹ̀ṣẹ, ki a le fi ileri nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi fun awọn ti o gbagbọ́.

23. Ṣugbọn ki igbagbọ́ to de, a ti pa wa mọ́ labẹ ofin, a si sé wa mọ́ de igbagbọ́ ti a mbọwa fihàn.

24. Nitorina ofin ti jẹ olukọni lati mu ni wá sọdọ Kristi, ki a le da wa lare nipa igbagbọ́.

25. Ṣugbọn lẹhin igbati igbagbọ́ ti de, awa kò si labẹ olukọni mọ́.

26. Nitoripe ọmọ Ọlọrun ni gbogbo nyin, nipa igbagbọ́ ninu Kristi Jesu.

27. Nitoripe iye ẹnyin ti a ti baptisi sinu Kristi, ti gbe Kristi wọ̀.

28. Kò le si Ju tabi Hellene, ẹrú tabi omnira, ọkunrin tabi obinrin: nitoripe ọ̀kan ni gbogbo nyin jẹ ninu Kristi Jesu.

Ka pipe ipin Gal 3