orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Efe 6 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ọmọ ati Òbí

1. ẸNYIN ọmọ, ẹ mã gbọ ti awọn õbi nyin ninu Oluwa: nitoripe eyi li o tọ́.

2. Bọ̀wọ fun baba ati iya rẹ (eyi ti iṣe ofin ikini pẹlu ileri),

3. Ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wà pẹ li aiye.

4. Ati ẹnyin baba, ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu: ṣugbọn ẹ mã tọ́ wọn ninu ẹkọ́ ati ikilọ Oluwa.

Ẹrú ati Ọ̀gá

5. Ẹnyin ọmọ-ọdọ, ẹ mã gbọ ti awọn oluwa nyin nipa ti ara, pẹlu ibẹru ati iwarìri, ni otitọ ọkàn nyin, bi ẹnipe si Kristi;

6. Ki iṣe ti arojuṣe bi awọn ti nwù enia; ṣugbọn gẹgẹ bi awọn ẹrú Kristi, ẹ mã ṣe ifẹ Ọlọrun lati inu wá;

7. Ẹ mã fi inu rere sin bi si Oluwa, kì si iṣe si enia:

8. Bi ẹnyin ti mọ pe ohun rere kohunrere ti olukuluku ba ṣe, on na ni yio si gbà pada lọdọ Oluwa, ibã ṣe ẹrú, tabi omnira.

9. Ati ẹnyin oluwa, ẹ mã ṣe ohun kanna si wọn, ẹ mã din ibẹru nyin kù; bi ẹnyin ti mọ pe Oluwa ẹnyin tikaranyin si mbẹ li ọrun; kò si si ojuṣãju enia lọdọ rẹ̀.

Ìjàkadì pẹlu Ibi

10. Lakotan, ará mi, ẹ jẹ alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara ipá rẹ̀.

11. Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, ki ẹnyin ki o le kọ oju ija si arekereke Eṣu.

12. Nitoripe kì iṣe ẹ̀jẹ ati ẹran-ara li awa mba jijakadi, ṣugbọn awọn ijoye, awọn ọlọla, awọn alaṣẹ ibi òkunkun aiye yi, ati awọn ẹmí buburu ni oju ọrun.

13. Nitorina ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀ ki ẹnyin ki o le duro tiri si ọjọ ibi, nigbati ẹnyin bá si ti ṣe ohun gbogbo tan, ki ẹ si duro.

14. Ẹ duro nitorina lẹhin ti ẹ ti fi àmure otitọ di ẹgbẹ nyin, ti ẹ si ti di ìgbaiya ododo nì mọra;

15. Ti ẹ si ti fi imura ihinrere alafia wọ̀ ẹsẹ nyin ni bàta;

16. Léke gbogbo rẹ̀, ẹ mu apata igbagbọ́, nipa eyiti ẹnyin ó le mã fi paná gbogbo ọfa iná ẹni ibi nì.

17. Ki ẹ si mu aṣibori igbala, ati idà Ẹmí, ti iṣe ọ̀rọ Ọlọrun:

18. Pẹlu gbogbo adura ati ẹbẹ ni ki ẹ mã gbadura nigbagbogbo ninu Ẹmí, ki ẹ si mã ṣọra si i ninu iduroṣinṣin gbogbo, ati ẹ̀bẹ fun gbogbo enia mimọ́;

19. Ati fun mi, ki a le fi ohùn fun mi, ki emi ki o le mã fi igboiya yà ẹnu mi, lati mã fi ohun ijinlẹ ihinrere hàn,

20. Nitori eyiti emi jẹ ikọ̀ ninu ẹ̀wọn: ki emi ki o le mã fi igboiya sọ̀rọ ninu rẹ̀, gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati mã sọ.

Gbolohun Ìparí

21. Ṣugbọn ki ẹnyin pẹlu ki o le mọ̀ bi nkan ti ri fun mi, bi mo ti nṣe si, Tikiku arakunrin olufẹ ati iranṣẹ olõtọ ninu Oluwa, yio sọ ohun gbogbo di mimọ̀ fun nyin:

22. Ẹniti mo rán si nyin nitori eyi kanna, ki ẹ le mọ bi a ti wà, ki on ki o le tu ọkàn nyin ninu.

23. Alafia fun awọn ará, ati ifẹ pẹlu igbagbọ́, lati ọdọ Ọlọrun Baba wá, ati Oluwa Jesu Kristi.

24. Ki ore-ọfẹ wà pẹlu gbogbo awọn ti o fẹ Oluwa wa Jesu Kristi li aiṣẹ̀tan.