Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Efe 5:18-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ẹ má si ṣe mu waini li amupara, ninu eyiti rudurudu wà; ṣugbọn ẹ kún fun Ẹmí;

19. Ẹ si mã bá ara nyin sọ̀rọ ninu psalmu, ati orin iyìn, ati orin ẹmí, ẹ mã kọrin, ki ẹ si mã kọrin didun li ọkàn nyin si Oluwa;

20. Ẹ mã dupẹ nigbagbogbo fun ohun gbogbo lọwọ Ọlọrun, ani Baba, li orukọ Jesu Kristi Oluwa wa;

21. Ẹ mã tẹriba fun ara nyin ni ìbẹru Ọlọrun.

22. Ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin, gẹgẹ bi fun Oluwa.

23. Nitoripe ọkọ ni iṣe ori aya, gẹgẹ bi Kristi ti ṣe ori ijọ enia rẹ̀: on si ni Olugbala ara.

24. Nitorina gẹgẹ bi ijọ ti tẹriba fun Kristi, bẹ̃ si ni ki awọn aya ki o mã ṣe si ọkọ wọn li ohun gbogbo.

25. Ẹnyin ọkọ, ẹ fẹran awọn aya nyin, gẹgẹ bi Kristi si ti fẹran ìjọ, ti o si fi ara rẹ̀ fun u;

26. Ki on ki o le sọ ọ di mimọ́ lẹhin ti a ti fi ọ̀rọ wẹ ẹ mọ́ ninu agbada omi,

27. Ki on ki o le mu u wá sọdọ ara rẹ̀ bi ìjọ ti o li ogo li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni; ṣugbọn ki o le jẹ mimọ́ ati alaini àbuku.

28. Bẹ̃li o tọ́ ki awọn ọkunrin ki o mã fẹràn awọn aya wọn gẹgẹ bi ara awọn tikarawọn. Ẹniti o ba fẹran aya rẹ̀, o fẹran on tikararẹ̀.

29. Nitori kò si ẹnikan ti o ti korira ara rẹ̀; bikoṣepe ki o mã bọ́ ọ ki o si mã ṣikẹ rẹ̀ gẹgẹ bi Kristi si ti nṣe si ìjọ.

30. Nitoripe awa li ẹ̀ya-ara rẹ̀, ati ti ẹran-ara rẹ̀, ati ti egungun ara rẹ̀.

31. Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ, on o si dàpọ mọ́ aya rẹ̀, awọn mejeji a si di ara kan.

32. Aṣiri nla li eyi: ṣugbọn emi nsọ nipa ti Kristi ati ti ijọ.

33. Ṣugbọn ki olukuluku nyin ki o fẹran aya rẹ̀ bẹ̃ gẹgẹ bi on tikararẹ̀; ki aya ki o si bẹru ọkọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Efe 5