Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sek 5:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni mo yipadà, mo si gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, iwe-kiká ti nfò.

2. O si wi fun mi pe, Kini iwọ ri? Emi si dahùn pe, mo ri iwe-kiká ti nfò; gigùn rẹ̀ jẹ ogún igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ igbọnwọ mẹwa.

3. O si wi fun mi pe, Eyi ni ègun ti o jade lọ si gbogbo ilẹ aiye: nitori gbogbo awọn ti o ba jale ni a o ke kuro lati ihin lọ nipa rẹ̀; gbogbo awọn ti o ba si bura ni a o ke kuro lati ihin lọ nipa rẹ̀.

4. Emi o mu u jade, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, yio si wọ̀ inu ile olè lọ, ati inu ile ẹniti o ba fi orukọ mi bura eke: yio si wà li ãrin ile rẹ̀, yio si run u pẹlu igi ati okuta inu rẹ̀.

5. Angeli ti mba mi sọ̀rọ si jade lọ, o si wi fun mi pe, Gbe oju rẹ si oke nisisiyi, ki o si wò nkan yi ti o jade lọ.

6. Mo si wipe, Kini nì? O si wipe, Eyi ni òṣuwọn efà ti o jade lọ. O si wipe, Eyi ni àworan ni gbogbo ilẹ aiye.

Ka pipe ipin Sek 5