Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rut 1:4-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nwọn si fẹ́ aya ninu awọn obinrin Moabu; orukọ ọkan a ma jẹ́ Orpa, orukọ ekeji a si ma jẹ́ Rutu: nwọn si wà nibẹ̀ nìwọn ọdún mẹwa.

5. Awọn mejeji, Maloni ati Kilioni, si kú pẹlu; obinrin na li o si kù ninu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji ati ọkọ rẹ̀.

6. Nigbana li o dide pẹlu awọn aya-ọmọ rẹ̀, ki o le pada lati ilẹ Moabu wá: nitoripe o ti gbọ́ ni ilẹ Moabu bi OLUWA ti bẹ̀ awọn enia rẹ̀ wò ni fifi onjẹ fun wọn.

7. O si jade kuro ni ibi ti o gbé ti wà, ati awọn aya-ọmọ rẹ̀ mejeji pẹlu rẹ̀; nwọn si mu ọ̀na pọ̀n lati pada wá si ilẹ Juda.

8. Naomi si wi fun awọn aya-ọmọ rẹ̀ mejeji pe, Ẹ lọ, ki olukuluku pada lọ si ile iya rẹ̀: ki OLUWA ki o ṣe rere fun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin ti ṣe fun awọn okú, ati fun mi.

9. Ki OLUWA ki o fi fun nyin ki ẹnyin le ri isimi, olukuluku nyin ni ile ọkọ rẹ̀. Nigbana li o fi ẹnu kò wọn lẹnu; nwọn si gbé ohùn wọn soke nwọn si sọkun.

10. Nwọn si wi fun u pe, Nitõtọ awa o bá ọ pada lọ sọdọ awọn enia rẹ.

11. Naomi si wipe, Ẹnyin ọmọbinrin mi ẹ pada: ẽṣe ti ẹnyin o fi bá mi lọ? mo ha tun ní ọmọkunrin ni inu mi, ti nwọn iba fi ṣe ọkọ nyin?

12. Ẹ pada, ẹnyin ọmọbinrin mi, ẹ ma lọ; nitori emi di arugbo jù ati ní ọkọ. Bi emi wipe, Emi ní ireti, bi emi tilẹ ní ọkọ li alẹ yi, ti emi si bi ọmọkunrin;

13. Ẹnyin ha le duro dè wọn titi nwọn o fi dàgba? Ẹnyin o le duro dè wọn li ainí ọkọ? Rara o, ẹnyin ọmọbinrin mi; nitoripe inu mi bàjẹ́ gidigidi nitori nyin, ti ọwọ́ OLUWA fi jade si mi.

Ka pipe ipin Rut 1