Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 27:11-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Ọmọ mi, ki iwọ ki o gbọ́n, ki o si mu inu mi dùn; ki emi ki o le da ẹniti ngàn mi lohùn.

12. Amoye enia ri ibi tẹlẹ, o si pa ara rẹ̀ mọ́; ṣugbọn awọn òpe kọja a si jẹ wọn niya.

13. Gbà aṣọ rẹ̀ nitoriti o ṣe onigbọwọ alejo, si gbà ohun ẹri lọwọ rẹ̀ fun ajeji obinrin.

14. Ẹniti o ba ndide ni kutukutu ti o nfi ohùn rara kí ọrẹ́ rẹ̀, egún li a o kà a si fun u.

15. Ọṣọrọ-òjo li ọjọ òjo, ati onija obinrin, bakanna ni.

16. Ẹnikẹni ti o pa a mọ́, o pa ẹfũfu mọ́, ororo ọwọ-ọtún rẹ̀ yio si fihàn.

17. Irin a ma pọn irin: bẹ̃li ọkunrin ipọn oju ọrẹ́ rẹ̀.

18. Ẹnikẹni ti o tọju igi-ọpọtọ yio jẹ eso rẹ̀; bẹ̃li ẹniti o duro tì oluwa rẹ̀ li a o buyì fun.

19. Bi oju ti ikò oju li omi, bẹ̃li aiya enia si enia.

20. Ipò-okú ati iparun kì ikún, bẹ̃ni kì isu oju enia.

21. Bi koro fun fadaka, ati ileru fun wura, bẹ̃li enia si iyìn rẹ̀.

22. Bi iwọ tilẹ fi ọmọri-odó gún aṣiwère ninu odo larin alikama, wère rẹ̀ kì yio fi i silẹ.

Ka pipe ipin Owe 27