Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 27:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MÁṢE leri ara rẹ niti ọjọ ọla, nitoriti iwọ kò mọ̀ ohun ti ọjọ kan yio hù jade.

2. Jẹ ki ẹlomiran ki o yìn ọ, ki o máṣe ẹnu ara rẹ; alejo, ki o má si ṣe ète ara rẹ.

3. Okuta wuwo, yanrin si wuwo, ṣugbọn ibinu aṣiwère, o wuwo jù mejeji lọ.

4. Ibinu ni ìka, irunu si ni kikún-omi; ṣugbọn tani yio duro niwaju owú.

5. Ibawi nigbangba, o san jù ifẹ ti o farasin lọ.

6. Otitọ li ọgbẹ ọrẹ́: ṣugbọn ifẹnukonu ọta li ẹ̀tan.

7. Ọkàn ti o yó fi ẹsẹ tẹ afara-oyin; ṣugbọn ọkàn ti ebi npa, ohun kikoro gbogbo li o dùn.

8. Bi ẹiyẹ ti ima fò kiri lati inu itẹ́ rẹ̀, bẹ̃li enia ti o nrìn kiri jina si ipò rẹ̀.

9. Ororo ati turari mu ọkàn dùn: bẹ̃ni adùn ọrẹ ẹni nipa ìgbimọ atọkànwa.

10. Ọrẹ́ rẹ ati ọrẹ́ baba rẹ, máṣe kọ̀ silẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe lọ si ile arakunrin li ọjọ idãmu rẹ: nitoripe aladugbo ti o sunmọ ni, o san jù arakunrin ti o jina rere lọ.

11. Ọmọ mi, ki iwọ ki o gbọ́n, ki o si mu inu mi dùn; ki emi ki o le da ẹniti ngàn mi lohùn.

Ka pipe ipin Owe 27