Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 26:10-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Bi tafatafa ti o mu gbogbo enia gbọgbẹ, bẹ̃ni ẹniti o gbà aṣiwère si iṣẹ, ti o si gba awọn olurekọja si iṣẹ-owo.

11. Bi aja ti ipada sinu ẽbì rẹ̀, bẹ̃li aṣiwère itun pada sinu wère rẹ̀.

12. Iwọ ri ẹnikan ti o gbọ́n li oju ara rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ.

13. Ọlẹ enia wipe, Kiniun mbẹ li ọ̀na; kiniun mbẹ ni igboro.

14. Bi ilẹkun ti iyi lori ìwakun rẹ̀, bẹ̃li ọlẹ lori ẹní rẹ̀.

15. Ọlẹ pa ọwọ rẹ̀ mọ́ sinu iṣãsun; kò si le yọ ọ jade pada wá si ẹnu rẹ̀.

16. Ọlẹ gbọ́n li oju ara rẹ̀ jù enia meje lọ ti nwọn le fi ọgbọ́n dahùn ọ̀ran.

17. Ẹniti nkọja lọ, ti o si dasi ìja ti kì iṣe tirẹ̀, o dabi ẹniti o mu ajá leti.

18. Bi asiwin ti nsọ ọ̀kọ, ọfa ati ikú,

19. Bẹ̃li ẹniti o tan ẹnikeji rẹ̀ jẹ, ti o si wipe, Iré ha kọ li emi nṣe?

20. Nigbati igi tan, ina a kú, bẹ̃ni nigbati olofofo kò si, ìja a da.

21. Bi ẹyin ti ri si ẹyin-iná, ati igi si iná; bẹ̃li enia onijà lati da ìja silẹ.

22. Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ.

23. Ete jijoni, ati aiya buburu, dabi idarọ fadaka ti a fi bò ìkoko.

Ka pipe ipin Owe 26