Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Owe 24:1-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. IWỌ máṣe ilara si awọn enia buburu, bẹ̃ni ki o má si ṣe fẹ lati ba wọn gbe.

2. Nitoriti aiya wọn ngbiro iparun, ète wọn si nsọ̀rọ ìwa-ika.

3. Ọgbọ́n li a fi ikọ ile; oye li a si fi ifi idi rẹ̀ kalẹ.

4. Nipa ìmọ ni iyará fi ikún fun oniruru ọrọ̀ iyebiye ati didùn.

5. Ọlọgbọ́n enia li agbara: nitõtọ enia ìmọ a sọ agbara rẹ̀ di pupọ.

6. Nitori nipa ìgbimọ ọgbọ́n ni iwọ o fi ṣigun rẹ: ati ninu ọ̀pọlọpọ ìgbimọ ni iṣẹgun.

7. Ọgbọ́n ga jù aṣiwère lọ: on kì yio yà ẹnu rẹ̀ ni ẹnu-bode.

8. Ẹniti nhùmọ ati ṣe ibi li a o pè li enia ìwa-ika.

9. Ironu wère li ẹ̀ṣẹ; irira ninu enia si li ẹlẹgàn.

10. Bi iwọ ba rẹwẹsi li ọjọ ipọnju, agbara rẹ ko to nkan.

11. Bi iwọ ba fà sẹhin ati gbà awọn ti a wọ́ lọ sinu ikú, ati awọn ti a yàn fun pipa.

12. Ti iwọ si wipe, wò o, awa kò mọ̀ ọ; kò ha jẹ pe ẹniti ndiwọ̀n ọkàn nkiyesi i? ati ẹniti npa ọkàn rẹ mọ́, on li o mọ̀, yio si san a fun enia gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.

13. Ọmọ mi, jẹ oyin, nitoriti o dara; ati afara oyin, ti o dùn li ẹnu rẹ:

14. Bẹ̃ni ìmọ ọgbọ́n yio ri si ọkàn rẹ: bi iwọ ba ri i, nigbana ni ère yio wà, a kì yio si ke ireti rẹ kuro.

15. Máṣe ba ni ibuba bi enia buburu, lati gba ibujoko olododo: máṣe fi ibi isimi rẹ̀ ṣe ijẹ.

16. Nitoripe olõtọ a ṣubu nigba meje, a si tun dide: ṣugbọn enia buburu yio ṣubu sinu ibi.

17. Máṣe yọ̀ nigbati ọta rẹ ba ṣubu, má si ṣe jẹ ki inu rẹ ki o dùn nigbati o ba kọsẹ̀:

18. Ki Oluwa ki o má ba ri i, ki o si buru li oju rẹ̀, on a si yi ibinu rẹ̀ pada kuro lori rẹ̀.

Ka pipe ipin Owe 24