17. Máṣe jẹ ki aiya rẹ ki o ṣe ilara si awọn ẹ̀lẹṣẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o wà ni ibẹ̀ru Oluwa, li ọjọ gbogbo.
18. Nitoripe ikẹhin mbẹ nitõtọ; ireti rẹ kì yio si ke kuro.
19. Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki iwọ ki o si gbọ́n, ki iwọ ki o si ma tọ́ aiya rẹ si ọ̀na titọ.
20. Máṣe wà ninu awọn ọmuti; ninu awọn ti mba ẹran-ara awọn tikarawọn jẹ.
21. Nitoripe ọmuti ati ọjẹun ni yio di talaka; ọlẹ ni yio si fi akisa bò ara rẹ̀.
22. Fetisi ti baba rẹ ti o bi ọ, má si ṣe gàn iya rẹ, nigbati o ba gbó.
23. Ra otitọ, ki o má si ṣe tà a; ọgbọ́n pẹlu ati ẹkọ́, ati imoye.
24. Baba olododo ni yio yọ̀ gidigidi: ẹniti o si bi ọmọ ọlọgbọ́n, yio ni ayọ̀ ninu rẹ̀.
25. Baba rẹ ati iya rẹ yio yọ̀, inu ẹniti o bi ọ yio dùn.
26. Ọmọ mi, fi aiya rẹ fun mi, ki o si jẹ ki oju rẹ ki o ni inu-didùn si ọ̀na mi.