12. Ireti pipẹ mu ọkàn ṣàisan; ṣugbọn nigbati ifẹ ba de, igi ìye ni.
13. Ẹnikan ti o ba gàn ọ̀rọ na li a o parun: ṣugbọn ẹniti o bẹ̀ru ofin na, li a o san pada fun.
14. Ofin ọlọgbọ́n li orisun ìye, lati kuro ninu okùn ikú.
15. Oye rere fi ojurere fun ni; ṣugbọn ọ̀na awọn olurekọja ṣoro.
16. Gbogbo amoye enia ni nfi ìmọ ṣiṣẹ; ṣugbọn aṣiwere tan were rẹ̀ kalẹ.
17. Oniṣẹ buburu bọ́ sinu ipọnju; ṣugbọn olõtọ ikọ̀ mu ilera wá.
18. Oṣi ati itiju ni fun ẹniti o kọ̀ ẹkọ́; ṣugbọn ẹniti o ba fetisi ibawi li a o bu ọlá fun.
19. Ifẹ ti a muṣẹ dùnmọ ọkàn; ṣugbọn irira ni fun aṣiwere lati kuro ninu ibi.