1. NITORI nkan yi ni mo rò li aiya mi, ani lati wadi gbogbo eyi pe, olododo, ati ọlọgbọ́n, ati iṣẹ wọn, lọwọ Ọlọrun li o wà: ifẹni ati irira, kò si ẹniti o mọ̀, gbogbo eyi wà niwaju wọn.
2. Bakanna li ohun gbogbo ri fun gbogbo wọn: ohun kanna li o nṣe si olododo, ati si ẹni buburu; si enia rere, ati si mimọ́ ati si alaimọ́; si ẹniti nrubọ, ati si ẹniti kò rubọ: bi enia rere ti ri, bẹ̃ li ẹ̀lẹṣẹ; ati ẹniti mbura bi ẹniti o bẹ̀ru ibura.
3. Eyi ni ibi ninu ohun gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn, pe iṣẹ kanna ni si gbogbo wọn: ati pẹlu, aiya awọn ọmọ enia kún fun ibi, isinwin mbẹ ninu wọn nigbati wọn wà lãye, ati lẹhin eyini; nwọn a lọ sọdọ awọn okú.
4. Nitoripe tali ẹniti a yàn, ti ireti alãye wà fun: nitoripe ãye ajá san jù okú kiniun lọ.
5. Nitori alãye mọ̀ pe awọn o kú; ṣugbọn awọn okú kò mọ̀ ohun kan, bẹ̃ni nwọn kì ili ère mọ; nitori iranti wọn ti di igbagbe.
6. Ifẹ wọn pẹlu, ati irira wọn, ati ilara wọn, o parun nisisiyi; bẹ̃ni nwọn kò si ni ipin mọ lailai ninu ohun gbogbo ti a nṣe labẹ õrùn.
7. Ma ba tirẹ lọ, ma fi ayọ̀ jẹ onjẹ rẹ, ki o si mã fi inu-didun mu ọti-waini rẹ: nitoripe Ọlọrun tẹwọgba iṣẹ rẹ nisisiyi.
8. Jẹ ki aṣọ rẹ ki o ma fún nigbagbogbo; ki o má si jẹ ki ori rẹ ki o ṣe alaini ororo ikunra,
9. Ma fi ayọ̀ ba aya rẹ gbe ti iwọ fẹ ni gbogbo ọjọ aiye asan rẹ, ti o fi fun ọ labẹ õrùn ni gbogbo ọjọ asan rẹ: nitori eyini ni ipin tirẹ li aiye yi, ati ninu lãla ti iwọ ṣe labẹ õrùn.
10. Ohunkohun ti ọwọ rẹ ri ni ṣiṣe, fi agbara rẹ ṣe e; nitoriti kò si ete, bẹ̃ni kò si ìmọ, tabi ọgbọ́n, ni isa-okú nibiti iwọ nrè.