Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oni 3:8-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ìgba fifẹ, ati ìgba kikorira; ìgba ogun, ati ìgba alafia.

9. Ere kili ẹniti nṣiṣẹ ni ninu eyiti o nṣe lãla?

10. Mo ti ri ìṣẹ́ ti Ọlọrun fi fun awọn ọmọ enia lati ma ṣíṣẹ ninu rẹ̀.

11. O ti ṣe ohun gbogbo daradara ni ìgba tirẹ̀; pẹlupẹlu o fi aiyeraiye si wọn li aiya, bẹ̃li ẹnikan kò le ridi iṣẹ na ti Ọlọrun nṣe lati ipilẹṣẹ titi de opin.

12. Emi mọ̀ pe kò si rere ninu wọn, bikoṣe ki enia ki o ma yọ̀, ki o si ma ṣe rere li aiya rẹ̀.

13. Ati pẹlu ki olukulùku enia ki o ma jẹ ki o si ma mu, ki o si ma jadùn gbogbo lãla rẹ̀, ẹ̀bun Ọlọrun ni.

Ka pipe ipin Oni 3