Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oba 1:12-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ṣugbọn iwọ kì ba ti ṣiju wo ọjọ arakunrin rẹ ni ọjọ ti on di ajeji; bẹ̃ni iwọ kì ba ti yọ̀ lori awọn ọmọ Juda ni ọjọ iparun wọn; bẹ̃ni iwọ kì ba ti sọ̀rọ irera ni ọjọ wahala.

13. Iwọ kì ba ti wọ inu ibode awọn enia mi lọ li ọjọ idãmú wọn; nitotọ, iwọ kì ba ti ṣiju wo ipọnju wọn li ọjọ idãmú wọn, bẹ̃ni iwọ kì ba ti gbe ọwọ́ le ohun ini wọn li ọ̀jọ idãmú wọn.

14. Bẹ̃ni iwọ kì ba ti duro ni ikorita lati ké awọn tirẹ̀ ti o ti salà kuro; bẹ̃ni iwọ kì ba ti sé awọn tirẹ̀ ti o kù li ọjọ wahala mọ.

15. Nitori ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ sori gbogbo awọn keferi: bi iwọ ti ṣe, bẹ̃li a o si ṣe si ọ: ẹsan rẹ yio si yipada sori ara rẹ.

16. Nitori bi ẹnyin ti mu lori oke mimọ́ mi, bẹ̃ni gbogbo awọn keferi yio ma mu titi, nitõtọ, nwọn o mu, nwọn o si gbemì, nwọn o si wà bi ẹnipe nwọn kò ti si.

17. Ṣugbọn igbala yio wà lori oke Sioni, yio si jẹ mimọ́, awọn ara ile Jakobu yio si ni ini wọn.

18. Ile Jakobu yio si jẹ iná, ati ile Josefu ọwọ́-iná, ati ile Esau fun akeku-koriko, nwọn o si ràn ninu wọn, nwọn o si run wọn; kì yio si sí ẹniti yio kù ni ile Esau: nitori Oluwa ti wi i.

Ka pipe ipin Oba 1