Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Sol 4:2-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ehin rẹ dabi ọwọ́ ewurẹ ti a rẹ́ ni irun, ti o gòke lati ibi iwẹ̀ wá, olukulùku wọn bi èjirẹ, kò si si ọkan ti o yàgan ninu wọn.

3. Ete rẹ dabi owu òdodo, ohùn rẹ si dùn: ẹ̀rẹkẹ rẹ si dabi ẹlà pomegranate kan labẹ iboju rẹ.

4. Ọrùn rẹ dabi ile-iṣọ Dafidi ti a kọ́ fun ihamọra, lori eyi ti a fi ẹgbẹrun apata kọ́, gbogbo wọn jẹ asà awọn alagbara.

5. Ọmu rẹ mejeji dabi abo egbin kekere meji ti iṣe èjirẹ, ti njẹ lãrin itanna lili.

6. Titi ọjọ yio fi rọ̀, ti ojiji yio si fi fò lọ, emi o lọ si òke nla ojia, ati si òke kékeké turari.

7. Iwọ li ẹwà gbogbo, olufẹ mi; kò si abawọ́n lara rẹ!

8. Ki a lọ kuro ni Lebanoni, iyawo mi, ki a lọ kuro ni Lebanoni: wò lati ori òke Amana, lati ori òke Ṣeniri ati Hermoni, lati ibi ihò kiniun, lati òke awọn ẹkùn.

9. Iwọ ti gbà mi li ọkàn, arabinrin mi, iyawo! iwọ ti fi ọkan ninu ìwo oju rẹ, ati ọkan ninu ẹwọ̀n ọrùn rẹ gbà mi li ọkàn.

10. Ifẹ rẹ ti dara to, arabinrin mi, iyawo! ifẹ rẹ ti sàn jù ọti-waini to! õrùn ikunra rẹ si jù turari gbogbo lọ.

11. Iyawo! ète rẹ nkán bi afara-oyin: oyin ati wàra mbẹ labẹ ahọn rẹ; õrun aṣọ rẹ si dabi õrun Lebanoni.

12. Ọgbà ti a sọ ni arabinrin mi, iyawo! isun ti a sé, orisun ti a fi edidi dí.

13. Ohun gbigbìn rẹ agbala pomegranate ni, ti on ti eso ti o wunni; kipressi ati nardi.

Ka pipe ipin O. Sol 4