7. Wo akete rẹ̀, ti iṣe ti Solomoni; ọgọta akọni enia li o yi i ka ninu awọn akọni Israeli.
8. Gbogbo wọn li o di idà mu, nwọn gbọ́n ọgbọ́n ogun: olukulùku kọ́ idà rẹ̀ nitori ẹ̀ru li oru.
9. Solomoni, ọba, ṣe akete nla fun ara rẹ̀ lati inu igi Lebanoni.
10. O fi fadaka ṣe ọwọ̀n rẹ̀, o fi wura ṣe ibi ẹhin rẹ̀, o fi elese aluko ṣe ibujoko rẹ̀, inu rẹ̀ li o fi ifẹ tẹ́ nitori awọn ọmọbinrin Jerusalemu.
11. Ẹ jade lọ, Ẹnyin ọmọbinrin Sioni, ki ẹ si wò Solomoni, ọba, ti on ti ade ti iya rẹ̀ fi de e li ọjọ igbeyawo rẹ̀, ati li ọjọ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.