2. Emi o dide nisisiyi, emi o si rìn lọ ni ilu, ni igboro, ati li ọ̀na gbòro ni emi o wá ẹniti ọkàn mi fẹ: emi wá a, ṣugbọn emi kò ri i.
3. Awọn oluṣọ ti nrìn ilu yika ri mi: mo bère pe, Ẹ ha ri ẹniti ọkàn mi fẹ bi?
4. Ṣugbọn bi mo ti fi wọn silẹ gẹrẹ ni mo ri ẹniti ọkàn mi fẹ: mo dì i mu, emi kò si jọ̃rẹ̀ lọwọ, titi mo fi mu u wá sinu ile iya mi, ati sinu iyẹwu ẹniti o loyun mi.
5. Mo fi awọn abo egbin ati awọn abo agbọnrin igbẹ fi nyin bú, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ki ẹ máṣe rú olufẹ mi soke, ki ẹ má si ji i, titi yio fi wù u.
6. Tani eyi ti nti ijù jade wá bi ọwọ̀n ẽfin, ti a ti fi ojia ati turari kùn lara, pẹlu gbogbo ipara olõrun oniṣowo?
7. Wo akete rẹ̀, ti iṣe ti Solomoni; ọgọta akọni enia li o yi i ka ninu awọn akọni Israeli.