Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 85:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA, iwọ ti nṣe oju rere si ilẹ rẹ: iwọ ti mu igbekun Jakobu pada bọ̀.

2. Iwọ ti dari aiṣedede awọn enia rẹ jì, iwọ ti bò gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ.

3. Iwọ ti mu gbogbo ibinu rẹ kuro: iwọ ti yipada kuro ninu gbigbona ibinu rẹ.

4. Yi wa pada, Ọlọrun igbala wa, ki o si mu ibinu rẹ si wa ki o dá.

5. Iwọ o binu si wa titi lai? iwọ o fà ibinu rẹ jade lati irandiran?

6. Iwọ kì yio tun mu wa sọji: ki awọn enia rẹ ki o ma yọ̀ ninu rẹ?

7. Oluwa fi ãnu rẹ hàn fun wa, ki o si fun wa ni igbala rẹ.

8. Emi o gbọ́ bi Ọlọrun Oluwa yio ti wi: nitoriti yio sọ alafia si awọn enia rẹ̀, ati si awọn enia mimọ́ rẹ̀: ṣugbọn ki nwọn ki o má tun pada si were.

9. Nitõtọ igbala rẹ̀ sunmọ́ awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀; ki ogo ki o le ma gbé ilẹ wa.

Ka pipe ipin O. Daf 85