1. NI Juda li a gbe mọ̀ Ọlọrun: orukọ rẹ̀ si pọ̀ ni Israeli.
2. Ni Salemu pẹlu li agọ rẹ̀ wà, ati ibujoko rẹ̀ ni Sioni.
3. Nibẹ li o gbe ṣẹ́ ọfà, ọrun, apata, ati idà, ati ogun na.
4. Iwọ li ogo ati ọlá jù òke-nla ikogun wọnni lọ.
5. A kó awọn alaiya lile ni ikogun, nwọn ti sùn orun wọn, gbogbo ọkunrin alagbara kò si ri ọwọ wọn.
6. Nipa ibawi rẹ, Ọlọrun Jakobu, ati kẹkẹ́-ogun ati ẹṣin sun orun asunkú.
7. Iwọ, ani iwọ li o ni ìbẹru: ati tani yio le duro niwaju rẹ, nigbati iwọ ba binu lẹ̃kan?
8. Iwọ mu idajọ di gbigbọ́ lati ọrun wá: ilẹ aiye bẹ̀ru o si duro jẹ.