Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

O. Daf 69:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌLỌRUN, gbà mi; nitoriti omi wọnni wọ̀ inu lọ si ọkàn mi.

2. Emi rì ninu irà jijin, nibiti ibuduro kò si, emi de inu omi jijin wọnni, nibiti iṣan-omi ṣàn bò mi lori.

3. Agara ẹkun mi da mi: ọfun mi gbẹ: oju kún mi nigbati emi duro de Ọlọrun mi.

4. Awọn ti o korira mi lainidi jù irun ori mi lọ: awọn ti nṣe ọta mi laiṣẹ, ti iba pa mi run, nwọn lagbara: nigbana ni mo san ohun ti emi kò mu.

5. Ọlọrun, iwọ mọ̀ wère mi, ẹ̀ṣẹ mi kò si lumọ kuro loju rẹ.

6. Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, máṣe jẹ ki oju ki o tì awọn ti o duro de ọ nitori mi: máṣe jẹ ki awọn ti nwá ọ ki o damu nitori mi, Ọlọrun Israeli.

7. Nitoripe nitori tirẹ li emi ṣe nrù ẹ̀gan; itiju ti bo mi loju.

8. Emi di àjeji si awọn arakunrin mi, ati alejo si awọn ọmọ iya mi.

9. Nitori ti itara ile rẹ ti jẹ mi tan; ati ẹ̀gan awọn ti o gàn ọ, ṣubu lù mi.

10. Nigbati mo sọkun, ti mo si nfi àwẹ jẹ ara mi ni ìya, eyi na si di ẹ̀gan mi.

11. Emi fi aṣọ ọ̀fọ sẹ aṣọ mi pẹlu: mo si di ẹni-owe fun wọn.

12. Awọn ti o joko li ẹnu-bode nsọ̀rọ si mi; emi si di orin awọn ọmuti.

13. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, iwọ li emi ngbadura mi si, Oluwa, ni igba itẹwọgba: Ọlọrun, ninu ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ da mi lohùn, ninu otitọ igbala rẹ.

14. Yọ mi kuro ninu ẹrẹ̀, má si ṣe jẹ ki emi ki o rì: gbigbà ni ki a gbà mi lọwọ awọn ti o korira mi, ati ninu omi jijìn wọnni.

Ka pipe ipin O. Daf 69