9. Iwọ bẹ aiye wò, o si bomi rin i: iwọ mu u li ọrọ̀, odò Ọlọrun kún fun omi: iwọ pèse ọkàn wọn, nigbati iwọ ti pèse ilẹ bẹ̃.
10. Iwọ fi irinmi si aporo rẹ̀ pipọpìpọ: iwọ si tẹ́ ogulutu rẹ̀: iwọ fi ọwọ òjọ mu ilẹ rẹ̀ rọ̀: iwọ busi hihu rẹ̀.
11. Iwọ fi ore rẹ de ọdun li ade; ọrá nkán ni ipa-ọ̀na rẹ.
12. Papa-tutù aginju nkán: awọn òke kekèke fi ayọ̀ di ara wọn li àmure.
13. Agbo ẹran li a fi wọ̀ pápá-tútù na li aṣọ: afonifoji li a fi ọka bò mọlẹ: nwọn nhó fun ayọ̀, nwọn nkọrin pẹlu.